Shehu Sani: Àwọn agbébọn ṣèkọlù àdó olóró sí ojú irin Kaduna sí Abuja, orí ló kó wa yọ!

Abuja -Kaduna

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Sẹnetọ tẹlẹri to ṣoju ẹkun gbungbun Kaduna, Shehu Sani ti kede pe ori lo ko awọn yọ lọwọ ado oloro ninu ọkọ oju irin lọna Kaduna si Abuja.

Shehu Sani to fi iroyin naa lede ni ado oloro to ku lẹyin ti awọn agbesunmọmi ṣekọlu si ọkọ oju irin ni Ọjọọru ni ọkọ ou irin wọn gunle lori.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lori ẹrọ ayelujara ni Sani ti ni awọn agbesunmọmi naa ṣekọlu ọhun ki awọn to kọja, amọ awọn ado oloro naa ṣi wa ni oju popo naa.

O fikun un pe awọn agbesunmọmi naa tun dana ibọn bo ''enigine'' ọkọ ati ile epọ ọkọ oju irin naa.

'' Ni Ọjọru, awọn agbesunmọmi ṣekọlu si oju irin Kaduna si Abuja pẹlu ado oloro ti wọn si tun da ibọn bo ọkọ oju irin naa.

Shehu Sani

Oríṣun àwòrán, Others

''Laarọ oni, mo wa ninu ọkọ oju irin naa ni a tun gunle ado oloro miran, ori lo ko wa yọ lọwọ iku.''