NBS: Owó orí oúnjẹ wá sílẹ̀ lóṣù kẹsán lórílẹ̀èdè Nàìjíríà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ aṣeṣiro lorilẹede Naijiria, NBS ti kede pe owo ori awọn aṣayan ounjẹ kan lorilẹede Naijiria wa silẹ loṣu kẹsan ọdun 2018.
Ninu abajade iwadi rẹ kan to pe ni "Selected Food Price Watch'' eyi to tumọ si," ayẹwo iye owo awọn aṣayan ounjẹ kan" fun oṣu kẹsan ọdun 2018 eleyi to fi sita nilu Abuja lo ti sọ eyi di mimọ.
Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣe sọ, iye ti wọn n ta ẹyin agiriki wa silẹ lati N474.13 ti wọn taa ni oṣu kẹjọ si N472.73 ni oṣu kẹsan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakan naa lo tun juwe rẹ pe, iwọn kilo kan irẹsi pẹlu dinwo lati N375.02 to wa ninu oṣu kẹjọ si N371.32 ni oṣu kẹsan.
Abajade iwadi ajọ naa tun fi oju rẹ han sita pe iwọn kilo tomato pẹlu to jẹ N336.65 loṣu kẹjọ ti sun walẹ si N328.26 loṣu kẹsan.
Orisun: Ajọ aṣeṣiro lorilẹede Naijiria, Nigeria Bureau of Statistics, NBS.
Bakan naa, ni o ṣalaye pe ẹdinwo ba owo ori iṣu lasiko ayẹwo naa.
Amọṣa boya eyi so pọ mọ iriri awọn ọmọ Naijiria ni okọọkan awọn ọja kaakiri jẹ ibeere ti awọn eeyan ṣi n dahun si lori ikanni ayelujara gbogbo.












