Wo ẹgbẹ́ agbabọọlu méje tó pegedé fún ìpele 'Round of 16' Champions League pẹ̀lú Oriogbade FC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ti ipele akọkọ idije UEFA Champions League pari lalẹ ana Ọjọru ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kinni ọdun yii, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati ikọ agbabọọlu meje mii ti pegede fun ipele ''round of 16''.
Arsenal to ti n lewaju lori tabili Champions League lati ibẹrẹ idije naa fiya jẹ ikọ agbabọọlu Kairat Almaty pẹlu ami ayo mẹta si meji.
Eyi tumọ si pe gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ti Arsenal gba ni wọn bori ninu rẹ ni ipele akọkọ Champions League ti saa bọọlu yii.
Ẹlẹsẹ ayo Viktor Gyokeres lo kọkọ gba goolu sawọn fun Arsenal ki Kai Havertz to gba goolu keji wọle.
Gabriel Martinelli lo gba goolu kẹta wọle fun Oriogbade FC, bo tilẹ jẹ Kairat naa da meji pada.
Ẹgbẹ agbabọọlu Bayern Munich lo ṣe ipo keji lori tabili idije Champions League.
Liverpool lo wa ni ipo kẹta nigba ti Tottenham wa ni ipo kẹrin.
Ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lo ṣe ipo karun un, Chelsea lo wa ni ipo kẹfa.
Ikọ agbabọọlu Sporting CP lo gba ipo keje nigba ti Manchester City wa ni ipo kẹjọ.
Wọnyi ni awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo gba 'play-off' lati pegede fun ipele 'Round of 16' ni Champions League
Real Madrid
Inter
PSG
Newcastle United
Juventus
Atletico Madrid
Atalanta
Leverkusen
Dortmund
Olypiacos
Club Brugge
Galatasaray
AS Monaco
Qarabag FK
Bode/Glimt
Benfica












