NAFDAC: Ẹ̀yin ọmọ Naijiria, ẹ ṣóra fún ''Frozen Turkey, chicken'' àwọn ìkà ń fí ''Formalin'' sí i kó lè pẹ́

Ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun ati ounjẹ lorilẹede Naijiria, NAFDAC ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati ṣọra fun jijẹ adiyẹ tutu ti wọn n gbe si inu yinyin paapaa lati oke okun.

Ajọ NAFDAC ni awọn ika eniyan to n ta awọn adiye tutu ti wọn n gbe si inu yinyin yii lẹyin ti wọn ba ti fi ''formalin'' si inu rẹ.

Agbẹnusọ Ajọ NAFDAC, Dokita Abubakar Jimoh gba awọn Naijiria ni iyanju yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori ijamba ati ewu ti awọn ounjẹ inu yinyin yii n da si ara awọn eniyan.

Jimoh ni awọn ọlọja okunkun yii n fi formalin si inu awọn adiyẹ yii ki o ma le dabi tuntun ti wọn ṣẹṣẹ pa fun ọpọlọpọ ọjọ.

''Formalin ma n jẹ ki awọn ounjẹ yii dabi tuntun fin bii ọṣẹ melo ti wọn yoo fi ta a fun awọn araalu.''

''Amọ jijẹ ounjẹ ti wọn fi formalin gbe pamọ le e ṣe akoba fun agọ ara eniyan.''

''NAFDAC n pe akiyesi awọn ọmọ Naijiria si iwa buruku yii nitori awọn eniyan yii n gbe awọn ounjẹ yii wọle lẹyin ti ijọba apapọ ti fi ofin de.''

Bakan naa lo fikun un pe tita awọn ọja yii ko ni jẹ ki awọn to n ta adiyẹ ati awọn ohun ọṣin labẹle moribọ.

Formalin ni wọn fi ma n gbe awọn oku pamọ ni ile igbokusi ki o ma ba a run, ti wọn ba si fi si ounjẹ awọn eniyan, o le e fa aisan jẹjẹrẹ ẹjẹ fun awọn eniyan ati awọn aisan miran.