VAT Dispute in Supreme Court: Àwọn ìpínlẹ̀ Gúúsù-Gúúsù darapọ̀ mọ́ ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ gíga jùlọ

Awọn Gomina ipinlẹ to wa ni Guusu-Guusu Naijiria ti pinu lati darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn to n ba ijọba apapọ ṣẹjọ VAT.

Igbẹjọ lori ọrọ owo ori ọja VAT yi ti sun de ile ẹjọ giga lẹyin ti ijọba apapọ ni idajọ ti ile ẹjọ kọtẹmilọrun gbe kalẹ ko dun mọ awọn ninu.

Inu atẹjade onigun mẹfa kan ti wọn fi sita lọjọ Aje ni awọn Gomina wọn yi ti ni awọn ṣetan lati tako ajọ FIRS lori gbigba owo ori.

Gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa, to dari ipade wọn to waye ni Port Harcourt lo fi ọrọ yi to awọn akọroyin leti.

Yatọ si Okowa Gomina Nyesom Wike Rivers,,Godwin Obaseki,Edo,Emmanule Udom,Akwa Ibom ati Sẹnẹtọ Duoye Diri,Bayelsa peju sibi ipade naa.

Awọn Gomina yi tun sọ awọn ọrọ mi to ni ṣe pẹ pẹlu idagbasoke agbegbe wọn to fi mọ idasilẹ ikọ alaabo ti wọn naa.

Awọn ipinlẹ wo lo tako gbigba owo ori VAT

Igbesẹ awọn Gomina Guusu-Guusu Naijiria yi wa ni ibamu pẹlu ipinu awọn Gomina ẹkun iwọ oorun Guusu,South West.

Ṣaaju lawọn naa ti lawọn faramọ ki awọn ijọba ipinlẹ maa gba owo ori VAT yi.

Nibi ipade wọn to waye lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹsan ni Asaba ni wọn ti sọ ipinu yi ati awọn nkan miran to jẹ wọn logun.

Ipinlẹ bi Eko ati Rivers lo lewaju awọn to fẹ gba owo yi nitori wọn ti ṣe agbekalẹ ofin ti yoo fawọn oṣiṣẹ wọn lagbara lati gba owo yi dipo FIRS to n gba tẹlẹ.

Bayi ti awọn ipinlẹ Guusu-Guusu tun darapọ mọ wọn,iye wọn ti n pọ si.

Amọ ṣa awọn ipinlẹ bi Kano ati Katsina ti fariga pe awọn yoo kọdi gbigba owo VAT yi lati ọdọ awọn ijọba ipinlẹ.

Nibi tawọn wọn yi ti fi erongba wọn han, awọn ipinlẹ miran bi Kwara ko ti sọ boya awọn yoo faramọ igbesẹ yi.