Ghana: Kàyééfì! Ẹ wó ìyàwó tó ṣán ọkọ rẹ̀ mọ́lẹ̀ tó sí bẹ lórí !

Ileeṣẹ ọlọpaa ni orilẹede Ghana ti fi ọmọbinrin ọdun mẹtadinlọgbọn kan si panpẹ lẹyin to bẹ ori ọkọ rẹ.

Agbegbe ilu My God Village, ni iha ila oorun orilẹede naa ti iṣẹlẹ kayeefi yii ti waye.

Obinrin afurasi naa, Rachel Tetteh ni iyawo arakunrin ti wọn bẹ ori rẹ.

Iroyin abẹle gbe e pe ede aiyede lo waye laarin awọn tọkọ-taya mejeeji, eleyii to mu ki ọkọ fi ile si ilẹ to si gba oko nkan ọgbin lọ.

Amọ bi o ṣe n lọ ni oju ọna oko, ni afurasi to jẹ iyawo ọkunrin naa tẹlẹ, to si tii subu si ilẹ.

Lẹyin to ti ọkunrin naa subu tan , lo mu ada to si fi bẹ ori rẹ kuro ni ara rẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹkun ila oorun orilẹede naa, DSP Ebenezer Tetteh ni iṣẹlẹ yii waye ni nkan bi aago meje aabo, ni Ọjọ Aiku.

Tetteh ni lasiko ti awọn de ibi ti iṣẹlẹ ti waye, ni wọn ri oku ọkọ naa to wọ aṣọ funfun lori ṣokoto, ti ko si ori ni ara rẹ mọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii lori iṣẹlẹ yii mu ibẹru bojo ba awọn ara agbegbe Bosuso, to jẹ agbegbe awọn agbẹ oloko ni orilẹede naa.

Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti mu obinrin afurasi naa pẹlu ada to fi ṣe iṣẹ ibi naa gẹgẹ bi ẹri pe o pa ọkọ rẹ.

Bakan naa ni wọn fikun un pe iwadii ṣi n lọwọ lori iṣẹlẹ naa, ki wọn le fi idi gbogbo ohun to rọ mọ iṣẹlẹ naa lede fun awọn araalu.