Nigeria Resident Doctor's Strike: Àwọn dókítà tí fagilé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ, sùgbọ́n...

Àwọn ẹgbẹ́ dókítà tí fagilé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ ti wọ́n gùnlẹ, sùgbgọ́n wọ́n ṣe ìlérí pé, ọjọ́rú ni àwọn yóò tó wọṣẹ́.

Tí ẹ ò bá gbàgbé, àwọn dókítà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nínú oṣù kẹjọ lẹ́yìn èdè-àìyede tó bẹ́sílẹ̀ láàrín àwọn àti ìjọba àpapọ̀ lórí àwọn irinṣẹ́ àti ohunèlò tí kò tó láwọn ilé ìwòsàn ìjọba.

Nínú àtẹ̀jáde ti wọ́n fi sita lórí àfẹnukò wọn tí akọ̀wé ẹgbẹ́ náà Expe Philips Uche fọwọ́sí lẹ́yìn ìpàdé tí àwọn aṣojú NMA àti NARD ṣe nílùú Abuja ni bi ti ẹgbẹ́ àwọn Dókíta (NMA) tí wọ́n sì gbà wọ́n ni ìmọ̀ràn láti fòpin sí ìyànsẹ́lódì.

Nínú ìpàdé náà ẹgbẹ́ NMA paá ni dandan pé kí ìgbìmọ̀ tó n mójú tó mímójú tó àdéhùn ìjọba tí wọ́n fi ọwọ́ sí ni ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹjọ ọdún yìí ri dájú pé ìjọba mú àdéhùn wọn ṣẹ.

Bákan náà lo ni ki ìgbìmọ̀ ọ̀hún jábọ̀ padà fún àwọn alága NMA ìpińlẹ̀ kọ̀ọ̀kan tó fi mọ́ alága ti ilúi Abuja lóòrèkóòrè lórí ilọsíwájú tó bá wáyé.

Gẹ́gẹ́ bi alága NARD Godiya Ishaya ṣe sọ, ẹgbẹ́ tí fagilé òyànṣẹ́lódì.

Ó ní : " A ti fagilé ìyànṣẹ́lódì, à ọ sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní aago mẹ́jọ owúrọ̀ Ọjọ́rú. A p ẹnupọ̀ láti fagilé ìyànṣẹ́lódì yìí ní ìdájí owúrọ̀ òní."

"A pe ìpàdé pàjáwìrì ni ago márùn àbọ̀ ọj Aikú títí dí òwúrọ̀ òní, à jọ́ ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àṣeyọrí wa, a si wòó pé kí a fopin sí ìyànṣẹ́lódì tó n lọ."

Ọ̀sẹ̀ mẹ́sàn gbáko ni ìyànṣẹ́lódì náà pé ní òní ọjọ́ Ajé, èyí tí ó sì tí ṣe àkọ́bá fún àwọn ilé ìwòsàn ìjọba jákèjádò Nàìjíríà, tí ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn sì ti fara gbá nínú rẹ.