Female Private Part Odour: Ohun méta rèé tó ń fa kí abẹ́ obinrin má a rùn...

Orisirisi nkan lo le fa a ki oju ara obinrin ma a run yatọ si oorun ti o ba wa lati ọrun.

Lati ara ounjẹ jijẹ, ilera ara ati awọn nkan miran ma a n fa ki oorun oju ara yipada.

Ọpọlọpọ igba ni awọn eniyan ma n gbiyanju lati wa atunṣe si iṣoro yii nipa lilo awọn ohun oloorun tabi ọṣẹ, amọ eleyii lewu ni ọpọlọpọ igba.

Gẹgẹ bi obinrin, ti o ba ri i pe oju ara rẹ n run kọja bi o ṣe yẹ, abi omi abẹ yi pada si awọ ti ko ba ti tẹlẹ mu, o ṣeeṣe ko o ti ni kokoro oju ara tabi aisan miran.

Awọn ohun to le fa ki oju abẹ ma a run re e;

Nigba ti ''Condom'' ti o n lo ko ba ara rẹ mu:

Nigba miran awọn eroja ti wọn fi se rọba idabobo ''condom'' le ma ba ara rẹ mu

Kọndọọmu mi lasiko ibalopọ le ma ba ẹni to n lo o ni ara mu, eleyii to le e jẹ ki oju ara ma a run, tabi ki o ma a yun ẹni naa. Tiraka lati lo ẹya condom miran bọya yoo ba ọ lara mu.

Nipasẹ Kokoro aifojuri Bacteria Vaginosis (BV):

Ọkan gboogi lara awọn kokoro aifojuri re e to ma n fa ki oju abẹ ma a run. Aisan yii ma n bọ si ara obinrin lasiko ibalopo eleyii to le fa awọn arun miran si ara ti a ko ba tete bojuto.

O le fa ki oyun bajẹ lara obinrin to ba ni aisan kokoro aifojuri yii lara.

Awọn ounjẹ ti ko ṣe ara loore:

Opọ obinrin lo fẹran lati maa jẹ ipapanu ti ko ṣe ara wọn loore.

Nigba ti awọn eroja ara bii pH levels ara obinrn ko ba pe, o ṣeese ki oju ara rẹ ma a run.

Nitori naa, ẹ jẹ ounjẹ to jẹ ọrẹ aawọ to si n mu ara ji pepe.

Jijẹ eso ati ewebẹ se pataki pupọ fun obinrin ati wara naa ki gbogbo eroja ara wọn le maa ṣiṣẹ bi o ti yẹ.