Kenyan Woman: Aláboyún fi bílédìì gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀ ní Tanzania

Ileesẹ ọlọpaa orilẹ-ede Tanzania ti fidirẹmulẹ pe, lootọ ni arabinrin alaboyun kan ṣe iṣẹ abẹ fun ara rẹ, lati gbe ọmọ inu rẹ jade.

Obinrin naa, ẹni ọgbọn ọdun, Joyce Kalinda ni wọn sọ pe, o sọ ara rẹ di onimọ iṣegun oyinbo ọsan gangan, to si gbẹbi ara rẹ.

N ṣe ni Joyce mu bileedi, to si fi la ara a rẹ ni ikun, ko to o gbe ọmọ tuntun naa jade.

Ọjọbọ, ọgbọnjọ, oṣu Karun un, ọdun 2019, ni iṣẹlẹ yii waye ni ilu Kirando, to wa ni ẹkùn Rukwa l'orilẹ-ede Tanzania.

A gbọ pe wọn ti kọkọ gbe obinrin naa lọ sileewosan ilu Kirando fun itọju ko to o bimọ.

Amọ, ṣe lo sa kuro nileewosan, to si pada sile.

Igba to de ile lo ran ọmọ rẹ to kere julọ lati lọ ọ pe ẹgbọn oun kan wa, ni adugbo ti ko jinna si wọn.

Ni kete to si ku oun nikan sinu ile, lo mu bileedi, to la ikun ara rẹ, to si gbe ọmọ tuntun jade.

Igba ti ọmọ to ran niṣẹ pada de, lo ba iya rẹ ati ọmọ tuntun ninu ile, eyi lo si mu ko pariwo 'ẹ gba mi' si awọn alajọgbelepọ wọn fun iranlọwọ.

Wọn si pinnu lati gbe e pada sileewosan to ti sa kuro.

Ọmọ kẹjọ ti obinrin naa yoo bi niyii.

Igbesẹ arabinrin yii ti fa n ha-hin ni agbegbe naa.