Covid- 19 Vaccine: Ẹ wo àwọn adarí ìjọ ní Naijiria tó tako abẹ́rẹ́ àjẹ́sára Covid-19 àti àwọn tó faramọ

Ọpọlọpọ awọn adari ijọ lorilẹede Naijiria ni ero wọn ṣe ọtọọtọ lori gbigba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Naijiria lati tako ajakalẹ arun ọhun.

Bi awọn adari ile ijọsin kan ṣe n sọ wi pe o dara lati gba Covid-19 fun idaabobo ara ẹni lọwọ arun naa ati fun ipolongo ihinrere Jesu Krisiti lati orilẹede kan si omiran lai si idiwọ nitori arun Covid 19,

Ni awọn adari ijọ miran ni ko si ohun to le e mu wọn gba abẹrẹ ajẹsara naa nitori wọn kọ ọ, ti wọn ko si ni igbagbọ ninu rẹ.

Lara awọn adari ijọ to tako gbigba abẹrẹ ajẹsara naa ni Adari Ijọ Living Faith Church International (Winners Chapel), Bishop David Oyedepo; Adari Ijọ Omega Fire Ministries International, Apostle Johnson Suleman; Adari Ijọ Household of God Church International Ministries, Pastor Chris Okotie; Adari Ijọ Christ Embassy, Pastor Chris Oyakhilome.

Amọ, awọn adari ijọ kan ti wọn faramọ gbigba abẹrẹ ajẹsara Covid 19 ọhun ni Adari Ijọ Kingsway International Christian Centre, Pasitọ Matthew Ashimolowo; Adari Ijọ Redeemed Evangelical Mission, Dr Mike Okonkwo; Adari Ijọ Trinity House, Ituah Ighodalo; Adari Ijọ Daystar Christian Centre, Pasitọ Sam Adeyemi ati Adari Ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye to ni ohun yoo gba abẹrẹ ajẹsara naa lati polongo ihinrere Jesu Kristi.

Awọn adari ijọ to tako gbigba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 re e...

Bishop David Oyedepo lasiko ayẹyẹ ogoji ọdun ti wọn ti bẹrẹ ihinrere ni ile ijọsin rẹ ni Ota, nipinlẹ Ogun ti ni ohun kii ṣe ẹranko ti yoo gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19, nitori naa ohun ko nii gba abẹrẹ ajẹsara naa.

Bakan naa lo sọ fun awọn ijọ rẹ lati maṣe gba abẹrẹ ajẹsara naa nitori eroja iku ni wọn n pe ni abẹrẹ ajẹsara naa.

Bakan naa ni Apostle Johnson Suleman ni abẹrẹ ajẹsara naa ko fi ẹṣẹ mulẹ to, nitori naa ohun ko ni gba ẹnikẹni ni imọran lati gba abẹrẹ, ajẹsara naa.

Ninu ọrọ tirẹ, Chris Okotie ni abẹrẹ ajẹsara naa yoo mu ki awọn eniyan ma a wa ẹjẹ lati mu lẹyin ti wọn ba ti gba abẹrẹ ajẹsara naa tan nitori irinṣẹ esu ni abẹrẹ ajẹsara naa.

Ni Osu Kẹta ọdun 2021 yii ni Chris Oyakhilome bu ẹnu atẹ lu awọn iranṣẹ Ọlọrun miran ni Naijiria ti wọn n gba awọn ara ijọ wọn ni imọran lati gba abẹrẹ ajẹsara naa nitori ohun ti ko dara fun eniyan lati gba ni.

Awọn adari ijọ kan ti wọn faramọ gbigba abẹrẹ ajẹsara Covid 19 re e...

Bi o tilẹ jẹpẹ awọn adari ijọ kan ko faramọ, Ituah Ighodalo ninu ọrọ tirẹ ni ai ni imọ ni yoo mu ki eniyan ma a gbagbọ pe awọn ni igbagbọ lati bori arun kan nigba ti abẹrẹ ajẹsara wa nilẹ lati ṣe iranwọ fun idojuti arun naa.

Ninu ọrọ tirẹ, pasito Adeboye ni idi ti oun yoo fi gba abẹrẹ ajẹsara naa ni ti orilẹede kan ba kan an ni kanpa fun oun lati gba a,ki oun to le wọ orilẹede naa lati kede ihinrere Jesu Kristi.

Bakan naa lo gba awọn ọmọ ijọ rẹ lati gba abẹrẹ ajẹsara naa ti eru ajakalẹ arun Covid-19 ba n ba wọn, nitori o dara lati gba abẹrẹ ajẹsara naa ju ki eniyan ma a gbe ninu ibẹru-bojo lọ

Amọ awọn adari ijọ kan bi Adari Ijọ, Mountain of Fire and Miracles Ministries, Dr. Daniel Olukoya; Adari Ijọ Deeper Christian Life Ministry, Pasitọ William Kumuyi, Adari Ijọ The Sword of The Spirit Ministries International ati Adari Ijọ Pentecostal Fellowship of Nigeria, Bishop Wale Oke ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ìdí ti èmì náà yóò fi gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 rèé- Adeboye

Adari ati alákoso, ìjọ Redeemed Christian Church Of God Pásítọ̀ Enouch Adejare Adeboye, ti ṣàlàyé pé òun ṣetán láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 nítorí ìtànkálẹ̀ ìhìnrere Jesu.

Ó ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí lásìkò ìṣọ́-òrun olósooṣù ìjọ náà to wáye ni gbọ́gan ìpàgọ́ ìjọ náà ni mároṣẹ̀, Lagos/Ibadan.

Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin náà sọ pé àánú Ọlọ́run lo pa gbogbo ọmọ Nàìjíríà mọ́ lati ìgbà yìí wá, àti pé àwọn ti àsìkò wọn ti tó láti kú ni àwọn to kú.

Lásìkò tó ń ba ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ọmọ ìjọ náà sọ̀rọ̀, deboye ni, Ko si àsìkò kankan ti mo ti sọ fun yín pé kí ẹ ma gba àbẹ́rẹ́ àjẹsara Covid-19. 'Ẹ ò gbọ́ rí lẹ́nu mi'.

Kàkà tí ẹ ó fi máa gbé nínú ìbẹ̀rù bójójo, ẹ lọ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára, ti ẹ ba ro pé gbigba abẹ́rẹ́ náà ni yóò fi yin ni ọkàn balẹ̀, ẹ lọ gba ki ẹ le ni ifọkanbalẹ.

Baba Adeboye ṣàlàyé pé àwọn orílẹ̀-èdè kan wà ni àgbàyé ti wọ́n ni mí ò le wá sí orílẹ̀-èdẹ̀ àwọn ti mi o bá gba abẹ́rẹ́ Covid-19, Ko si nǹkan yti mi o lè ṣe fún Jesu."

" Ẹ má jẹ́ ki ń gba rárá pé, ẹnu mi ni ẹ ti gbọ pé kí ẹ ma gba abẹ́rẹ́ ajẹsara.

Adeboye ṣàlàyé pé nǹkan ti o pani lẹ́rin ni igbésẹ̀ àwọn gómínà kan tí wọ́n ni dandan ni abẹ́rẹ́ àjẹsara Covid-19 ki ènìyàn tó lọ sí ilé ìjọsìn.

Adeboye tọ́ka si pé irú àwọn adárí bẹ́ẹ̀ kùnà lati rii pé, àwọn abẹ́rẹ́ tó wa nilẹ̀ ko le tó fún àwọn ènìyàn tó wà nílẹ̀.

Nítori, ẹ̀yà Delta vatiant ni ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ti sọ abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 di nnkan to pọndandan láti wọ orílẹ̀-èdè mííràn.

Ó ti le ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ènìyàn tó ti ni ààrun