Togo: Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀yà kan wà ní Africa, tó jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nípa sí sọ nkan ọmọkùnrin di nla ní ìlànà ìbílẹ̀?

Lóòótọ́ ni iṣẹ́ abẹ wà, àmọ́ wo ẹ̀yà tó n fi kún nkan ọmọkùnrin láì ṣe iṣẹ́ abẹ.

Yoruba ní ki agbado to o de ayé, nkankan ni adiyẹ n jẹ.

Ko to o di pe ọlaju de, ti oriṣiriṣi ilana ti wọn n gba sọ nkan ọmọkùnrin di nla bẹrẹ, awọn eniyan ẹ̀yà Batammariba, ti a tun mọ si Somba, ni orilẹ-ede Togo ati Benin, ti jẹ́ akọṣẹmọṣẹ ninu sisọ nkan ọmọkùnrin di nla tabi ko gùn si.

Ni Benin, Somba ni wọn mọ wọn si. Agbegbe ori apata Atakora to wa ni aarin ibode ẹ̀yà Gur lorilẹ-ede Burkina Faso, si ni wọn n gbe.

Ni Togo, Ariwa Iwọ-oorun agbegbe Kara ni wọn n gbe pẹlu awọn ẹ̀yà Kabye.

Ilana ṣíṣe afikun sí nkan ọmọkùnrin jẹ ara eto ti wọn fi n gba àwọn ọdọmọkunrin to ti balaga si aarin àwọn agbalagba.

Lasiko eto naa, ewé kan ni wọn ma n gún, wọn o si fi pa nkan ọmọkùnrin naa. Lẹyin naa wọn o gé ẹka igi tabi ìwo, wọn o lu ihò si i lati fi ṣe àmì bi nkan ọmọkùnrin ẹni ti wọn n ṣe e fun yoo ṣe gùn tabi tobi tó.

Ọkùnrin naa yoo ki nkan ọmọkùnrin rẹ sinu iho igi naa fun oṣu diẹ, titi ti yoo fi gun tabi tobi to bose fẹ. Nigba naa ni yoo to o yọ jade.

Lasiko eto to kẹhin ti wọn yoo ṣe ni gbangba fun awọn ọkunrin naa, aṣọ olowo iyebíye ati owo ẹyọ ni wọn o fi ṣe ara wọn ni ọ̀sọ́.

Bakan naa ni wọn o fi fila ti wọn fi iwo ṣe de wọn lori.

Yatọ si ọgbọ́n sísọ nkan ọmọkùnrin di nla, àwọn eeyan naa tun gbajúmọ fun kikọ ile alarambara.