You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Online VAT: Sísan owó orí ọjà lórí ayélujára yóò mú kí ọrọ̀ ajé rú gọ́gọ́ si
Ajọ to n pawo wọle labẹle labẹ ijọba apapọ (FIRS) ti kede pe, oun yoo bẹrẹ si ni gba owo ori VAT, lori awọn ọja ti awọn ọmọ Naijiria ba ra lati ori ayelujara.
Igbesẹ sisan owo ori naa ni wọn sọ pe yoo bẹrẹ losu Kinni ọdun 2020, ti yoo si kan awọn ọja ti wọn ba ra lori ayelujara labẹle ati ni oke okun.
Babatunde Fowler, tii se alaga fun ajọ FIRS lo kede ọrọ yii nibi ipade apero kan to waye nilu Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ọmọ Nàíjíríà ló ṣiṣẹ́ takò mí ní Ireland kí ń má baà wọlé ìbò Káńsélọ̀ - Yemi Adenuga
- Aṣojú Seyí Makinde lásan ní mo jẹ, òṣìṣẹ́ gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún mi - Ọ̀dọ́mọdé Kọmísánà
- Èmi àti Bọla Tinubu fẹ́ lo ‘German Mercenaries’ láti gbé MKO Abiọla kúrò lẹ́wọ̀n - Dele Momodu
- Irọ́ ńlá! Ẹgbẹ́ IPOB ò tako Ààrẹ Buhari ní Japan- Iléeṣẹ́ Ààrẹ
- Òfin nìkan ló lè gbadé lórí àwa Ọba ìlú lbadan- Oba Lekan Balogun
- Irọ́ ló pa, a kò mọ̀ ọ́ rí tàbí fún ọ ní ₦13m - APC tako afurasí ajínigbé
Fowler ni ọpọ awọn orilẹede lo ri ilẹ wa Naijiria bii ọja nla ti wọn ti lee se okoowo wọn lori afẹfẹ, idi si ree ti Naijiria naa fi gbọdọ lo anfaani yii lati pawo wọle.
"Owo ori ọja jẹ ọna kan gboogi to n mu owo wa fun awọn orilẹede nilẹ adulawọ, to si maa n ko ida mọkanlelọgbọn ninu ọgọrun owo to n wọle nigba miran, eyi gan pọ ju iye ti ajọ to wa fun idagbasoke ọrọ aje n ri lọ tii se ida ogun ninu ọgọrun."
Amọ sa, Fowler ni asẹ wa lọwọ ijọba apapọ ti igbesẹ gbigba owo lori awọn ọja ti wọn ba ra lori ayelujara naa, yoo ba di ohun.