You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Japan visit: Iléeṣẹ́ ààrẹ ní ẹgbẹ́ IPOB kò tako Buhari ní Japan
Irọ funfun balau ni iroyin kan to n tan kaakiri lori ayelujara pe awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB ti wọn yabo igbakeji ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja tẹlẹ, Sẹnẹtọ Ike Ekweremadu lorilẹede Germany ṣewọde lati tako Aarẹ Muhammadu Buhari nigba to gunlẹ si orilẹede Japan lọjọ Aje.
Oludamọran pataki fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Femi Adesina lo sọ fawọn ọmọ Naijiria nile ati nilẹ okere pe iroyin ofege lawọn kan n gbe kiri.
Ọgbẹni Adesina ni awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB ko ni ohun kan ṣe pẹlu Aarẹ Buhari lati igba to ti de si ilu Yokohama lorilẹede Japan.
- Èmi àti Bọla Tinubu fẹ́ lo ‘German Mercenaries’ láti gbé MKO Abiọla kúrò lẹ́wọ̀n - Dele Momodu
- O dùn mí pé Buhari kò yàn mí sípò Mínísítà lẹ́ẹ̀kejì àmọ́ mò gbà kádàrá - Adebayo Shittu
- Buhari, ṣí ìwé àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn gómìnà tó jẹ̀bi ìkówójẹ, káráyé mọ̀ wọ́n - SERAP
- Òfin nìkan ló lè gbadé lórí àwa Ọba ìlú lbadan- Oba Lekan Balogun
- Èdè Akurẹ àti Ibadan ni wọ́n fi fà mí léti pé ẹni re kìí 'se òṣèlú - Seyi Makinde
- Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe mú mi lẹ́rú ní 1837 - Ajayi Crowther
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
Femi Adesina ni awọn ma ri ma sọ eeyan kan lo gbe iru iroyin yii kiri pẹlu ayederu fọnran lati tan ọpọlọpọ jẹ.
Oludamọran aarẹ kilọ fawọn to n gbe iroyin ofege kiri pe ki wọn jawọn lapọn ti ko yọ nitori ọrọ Naijiria ti kọja iru iwa bẹẹ.
O ni Buhari ṣetan lati ṣe nnkan iwuri fun gbogbo ọmọ Naijiria nibi apero to da lorim igbasoke ilẹ Afirika ẹlẹẹkeje iru rẹ TICAD7.
Gomina ipinlẹ Eko, Kwara, ati Borno lo kọwọ rin pẹlu aarẹ lọ si orilẹede Japan.