Yemi Adenuga: Olùdìbò Ireland kìí gba ìrẹsì, àmọ́ wàá dé ilé kọ̀ọ̀kan láti bèèrè ìbò

Agbohunsafẹfẹ ni Yemi Adenuga lorilẹede Naijiria ko to lọ tẹdo si orilẹede Ireland lọdun 2000.

Lọdun 2019 ta wa yii si lo dibo wọle gẹgẹ bii Kanselọ alawọ dudu akọkọ ti wọn yoo dibo yan lorilẹede Ireland.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Yemi Adenuga ni o se ni laanu pe awa alawọ dudu gangan ni ọta ara wa nitori awọn ọmọ Naijiria gan lo dide tako oun pe oun ko ni wọle ibo kanselọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn oludibo ni Ireland kii beere fun owo, asọ, ororo, irẹsi abi tomato, ohun kan soso ti eeyan gbọdọ se ni lati polongo ibo lọ si ojule kọọkan fun awọn oludibo.

Adenuga fikun pe, bi ilu se ri lo gbe oun kuro ni Naijiria, to fi mọ ọrọ ẹbi oun, wiwa ọjọ ọla fun awọn ọmọ ati ki iya oun lee jẹ ounjẹ ọmọ lọjọ alẹ.

Kanselọ alawọ dudu akọkọ ni Ireland naa wa rọ awọn ọmọ Naijiria nile ati loke okun, lati mu ayipada rere ba orukọ buruku ti wọn sọ orilẹede Naijiria lẹyin odi, ka si jẹ ki wọn mọ pe ohun rere lee ti orilẹede Naijiria jade wa, gẹgẹ bi oun ti se.