Òhun táa mọ̀ rèé nípa ìròyìn pé EFCC mú ìyàwó Gómìnà Ganduje ìpínlẹ̀ Kano

Hajiya Hafsat Ganduje to jẹ aya gomina ipinlẹ Kano, Abdulahi Ganduje to pada sile.

Iroyin naa fidi e mule pe o ti kuro ni ọgba ajọ EFCC to n mojuto iwa ajẹbanu ni Naijiria .

Saaju ni okan lara awọn amugbalẹgbé gomina Kano lori ifitonileti lori ayelujara fi lede pe Hajiya Hafsat ti n lọ si agọ EFCC ni Abuja.

Iroyin to gba igboro kan ni pe EFCC ti gbe aya gomina naa lalẹ ọjọ Aje.

Sugbọn ọkan lara awọn to sunmọ Gomina Ganduje ti ko fẹ ki a darukọ oun sọ fun BBC ni pe ọrọ ko ri bẹẹ.

Titi di asiko yii ko sẹni to le sọ nipato ohun ti aya gomina ba bọ lati EFCC s\ugbọn ohun to daju ni pe o lọ sibẹ.

Iroyin ni pe EFCC ti ranṣẹ pe aya gomina naa lọsẹ meloo kan sẹyin ko wa ṣalaye awọn nakn kọọkan ti ko si lọ.

Ṣé lóòótọ́ ní pé EFCC mú ìyàwó Gómìnà Ganduje ìpínlẹ̀ Kano?

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria EFCC ti mu iyawo Gomina ipinlẹ Kano,Hajia Hafsat Ganduje lori ẹsun iwa ajẹbanu ti ọmọ rẹ fi kan an.

Oṣiṣ ijọba ipinlẹ Kano kan ti o ni ka ma darukọ oun lo fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC.

O ni awọn oṣiṣẹ EFCC wa si Kano ti wọn si mu ''Gogo'' lọ si Abuja lati lọ dahun si awọn ibeere kan.

Amọ o ṣalaye fun BBC pe ifọrọwanilẹnuwo naa ti pari ti wọn si ti da pada sile,.

Ifọrọwanilẹnuwo lati ọdọ EFCC yi n waye lẹyin ti iwe iroyin Naijiria ti ṣaaju gbe pe Hajia Hafsat kọ lati dahun si iwe ipe ti EFCC fi ranṣẹ si.

Gẹgẹ bi awọn akọroyin ṣe sọ, ọmọ Hafsat,Abdulazeez Ganduje lo fi ẹsun kan iya rẹ lọdọ EFCC pe ọwọ iya rẹ ko mọ.

Ẹwẹ lowurọ ọjọ Iṣẹgun,loludamọran agba kan lori ọrọ ayelujara fun Gomina Ganduje Abubakar Aminu Ibrahim ṣe afihan aworan Gomina ati iyawo rẹ.

Ninu aworan yi to wa loju opo rẹ ni Facebook, o kọkọ kọ sibẹ pe awọn mejeeji n dari lati Abuja lẹyin irinajo.

Nigba ti yoo fi pẹ diẹ si igba naa lo tun kọ sibẹ pe Gomina ati iyawo rẹ lọ fun ipade kan ni Abuja.