Olubadan , Oba Saliu Adetunji rọ Báàlẹ̀ Lagelu Abọke, Oloye Saheed Alatise kúrò lóyè lórí ẹ̀sùn aṣemáṣe

Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Oba Saliu Adetunji ti yọ Oloye Saheed Alatiṣe nipo gẹgẹ bi i Baalẹ Lagelu Abọke ni ijọba ibilẹ Ido ipinlẹ Ọyọ.

Atẹjade ti awọn oniroyin ri gbamu lati ọwọ ẹni ti o jẹ agbẹnusọ fun Ọba Alade naa, Adẹọla Ọlọkọ ṣe alaye pe iyọninipo Baalẹ naa ti bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ.

Lara awọn iredi ti igbesẹ naa fi waye ni ẹsun ti wọn fi kan Baalẹ naa ni pe o kopa ninu rogbodiyan kan to waye ninu oṣu kẹẹsan ọdun 2017, lẹyin ti wọn fi jẹ Baalẹ tan.

Igbimọ lọbalọba Olubadan fi kun ọrọ wọn wi pe bi Baalẹ naa ṣe kọ lati wa wi tẹnu rẹ lori awọn ọkanojọkan ẹsun ti wọn fi kan an lo jẹ iwa arifin gbaa si Olubadan ti ilẹ Ibadan

Wọn ni iru iwa arifin yii yẹ fun ijiya ninu ilana aṣa ati iṣe ilẹ Ibadan.

Lara awọn ẹsun mii ti wọn fi kan Baalẹ ti wọn rọ loye naa ni pe o gba ọna eru lati fa ara rẹ kalẹ fun oye Baalẹ nigba ti ki i ṣe ojulowo ọmọkunrin ti wọn bi sinu idile naa.

Ninu iwe kan ti awọn ẹbi Lagelu Abọke kọ si Olubadan ẹleyii ti olori ẹbi naa, Ganiyu Oladokun Okerinu Aboke buwọ lu ni wọn ti tọka rẹ pe Arakunrin Saheed Alatiṣe ti o wa lati Agbede Adodo nilu Ibadan ko lẹtọ lati ṣoju mọlẹbi Abọke ni to n bẹ ni agbegbe Bẹẹrẹ, gẹgẹ bi i Baalẹ.