Juventus: Ronaldo gbáyò sáwọ̀n fún ìgbà àkọ́kọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹlẹsẹ ayo Cristiano Ronaldo fi idunnu rẹ han lẹyin to gba bọọlu sawọn fun igba akọkọ ninu idije Seria A lati gba to ti to fi ikọ Real Madrid silẹ darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Juventus.
Ayo meji ọtọtọ ni Ronaldo gba wọle bi Juventus ṣe fagba han Sassuolo pẹlu ami ayo meji sẹyọkan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ronaldo sọrọ lori opo Twitter ẹgbẹ agbabọọlu Juventus pe oun ti n ṣiṣẹ takuntakun lati igba t'oun ti darapọ mọ ikọ Juventus, bẹẹni awọn akẹgbẹ oun naa ṣi n ranwọ f'oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ronaldo to kuna lati gbayo kankan wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta akọkọ to gba ninu idije liigi Serie A gbayo akọkọ wọle ni iṣẹju aadọta gerege.
Ronaldo fi ikeji si lẹyin iṣẹju mẹẹdogun to gba lakọkọ sawọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ko da ayo mẹta ni Ronaldo ko ba sawọn ikọ alatako wọn Sassuolo ṣugbọn ẹsẹ rẹ tase nibi to ti fẹ bọọlu sawọn.
Nibayii ẹgbẹ agbabọọlu Juventus ti jawe olubori ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ti wọn ti ninu idije liigi Serie A ti wọn ti gba lati igba ti Ronaldo ti darapọ mọ wọn.