Carl Ikeme: Aṣọ́lé Nàìjírìa fẹ̀yìntì lẹ́yìn àrùn jẹjẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aṣọle fun ẹgbẹ agbọọlu Super Eagles Carl Ikeme ti kede wipe oun ti fẹyinti ninu ere bọọlu.
Ikeme to jẹ ọmọ ọdun mejilelọgbọn ni arun jẹjẹrẹ inu ẹjẹ ti dagunlẹ lati oṣu keje ọdun 2017.
Ikeme ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Wolves nilẹ Gẹeṣi to ti n gba bọọlu jẹun ninu ifẹsẹwọnsẹ to le ni igba ki o to fẹyinti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni oṣu kẹfa ni Ikeme kede lori opo Twitter rẹ pe ara oun ti n ya daadaa lẹhin ti o ti gba itọju fun ọdun kan.
O gbe igbesẹ lati fẹyin ti ninu ere bọọlu lẹyin ti o fọrọ lọ awọn oniṣegun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikeme ṣoju ikọ agbabọọlu Naijiria lẹmẹẹwa, bẹẹni wọn si fi orukọ rẹ ninu awọn agbabọọlu to ṣoju orilẹede naa ninu ife ẹyẹ agbaye ni Russia lati mọ riri rẹ.
Ikeme ki gbogbo eeyan ti wọn ṣe atilẹyin fun un lati ti o ti ni arun jẹjẹrẹ inu ẹjẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post








