You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọwọ́ Amotekun Osun tẹ afurasí mọkálíìkì tó n wú òkú fún ètùtù ọlà
Ọwọ ajọ alaabo Amotekun ti tẹ mọkaliki kan, Afeez Odusanya, fun ẹsun pe o yọ eyin oku lati fi ṣe etutu ọla.
Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa wa lara awọn afurasi ọdaran ti Amotekun fi oju wọn han nilu Osogbo, l'Ọjọru.
Oludari Amotekun nipinlẹ Osun, Ọgbẹni Amitolu Shittu, sọ fun awọn akọroyin pe, eyin mejila ni wọn ba lọwọ Odusanya, ti igbagbọ si wa pe ẹnu oku lo ti yọ wọn.
O ni awọn tun ba egungun ìka ọwọ meji lọwọ rẹ.
Ọgbẹni Shittu sọ pe afurasi naa ti kọkọ parọ pe babalawo ni oun, ti oun si ma n ṣe etutu ọla.
O tẹsiwaju pe Ilu Sagamu nipinlẹ Ogun ni afurasi naa n gbe, ṣugbọn ọwọ tẹ ni ilẹ isinku kan nilu Ilesa, nipinlẹ Osun, nibi to ti n wu oku.
- 'Ẹran ẹtu ni mo yìnbọn sí, àmọ́ òkú ìmáàmù ni mo bá nígbà tí mo fẹ́ gbe e'
- Lukman gbẹ̀yín ẹbí lọ bẹ́ orí ìkókó ti wọ́n sìn ní Abeokuta, àṣírí tú bó ṣe fẹ́ tàá
- 'Mo dáríji ẹni tó pa mí lọ́kọ́, mò sì gbà kí àwọn ọmọ wa fẹ́ ara wọn'
- Adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ síwájú lẹ́yìn tí afurasí kan tó lọ́wọ́ nínú ikú Timothy Adegoke ṣubú nílé ẹjọ́
Afurasi ọhun, Odusanya, sọ fun awọn akọroyin pe ọdun 2016 ni oun wu oku fun igba akọkọ, ati pe igba meji ni oun ti gbiyanju lati ṣe etutu ọla amọ to foriṣanpọn.
"Nibi ti mo ti n wu oku kan jade ni ilẹ isinku kan nilu Ilesa, eyi ti mo fẹ fi ṣe etutu ọla, ni ọwọ ti tẹ mi.
"Lati ọdun 2016 si ni mo ti ma n yọ ẹya ara awọn ti mo ba wu oku wọn fun etutu ọla, amọ ko jẹ́ fun mi."
O tẹsiwaju pe nibi ti oun ti n yọ eyin oku lọwọ ti tẹ oun.
O ni laarin ọgbọn iṣẹju ni oun fi ma n yọ eyin kan lẹnu oku nigba ti oun kọkọ bẹrẹ , ṣugbọn oun ti di akọṣẹmọṣẹ bayii.