You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Teenagers arrested in Ogun for rituals: Ilé ẹjọ́ ju ọmọkùnrin mẹ́rin tó fi olólùfẹ́ ọ̀kan lára wọn ṣe òògùn owó sí ẹ̀wọ̀n
Ile ẹjọ Majisireti kan nilu Abeokuta ti ju awọn ọdọmọkunrin mẹrin ti ọwọ tẹ lasiko ti wọn n fi ololufẹ ọkan lara wọn sẹ oogun owo.
Ọjọ Satide to kọja ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun mu awọn mẹrẹẹrin, Balogun Mustakeem (20), Majekodunmi Soliudeen (18), Abdulgafa Lukman (19) ati Waris Oladeinde(18), nibi ti wọn ni wọn ti n dana sun ori ọmọbinrin ti wọn pa, Sofiat Okeowo, ni adugbo Kugba nilu Abeokuta.
Ẹsun igbimọpọ ati ipaniyan ni wọn fi kan wọn.
Onidajọ I.O Abudu paṣẹ pe ki wọn o ju wọn si ọgba ẹwọn to wa ni Oba titi ti ileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Ogun yoo fi sọ igbesẹt o kan lori ọrọ wọn.
O si sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta.
Nigba ti ọwọ tẹ awọn ọdọmọkunrin naa, lẹyin ti ọdẹ adugbo kan fi ọrọ to awọn ọlọpaa leti, jẹwọ pe ori ayelujara Facebook ni ọkan lara wọn ti kọ̀ nipa bi wọn yoo ṣe ṣe oogun owo.
Lẹyin ti wọn kọ ọ ni wọn gbimọpọ lati lo Sofiat to jẹ ọrẹbinrin ọkan lara wọn.
Wọn jẹwọ fun ọlọpaa pe miliki ni awọn yoo fi ma a lo ẹbu ti wọn ba ri lara ori naa ki owo le de.
Ẹgbọn Sofiat to ba BBC Yoruba sọrọ ni ounjẹ alẹ ni ọmọbinrin ẹni ofun ọhun n se lọwọ, ko to o dagbere pe oun fẹ sare de ibi kan.
Ile ọrẹkunrin rẹ to lọ naa lo ti kagbako iku ojiji.
Ṣe lootọ ni oogun owo wa?
Babalawo kan ti BBC Yoruba ba sọrọ, Olukunle Idowu, sọ pe ko si nkan to n jẹ etutu ọla tabi oogun owo ninu Ifa.
O ni to ba jẹ pe o wa ni, oun paapaa yoo ti ni owo tabua lọwọ.
Eyi tako igbagbọ ọpọ eeyan pe awọn babalawo lo n ṣe oogun ọrọ fawọn ọdọmọde ti wọn n wa owo ojiji lasiko yii.
Lẹnu ọjọ mẹta yii, iroyin fifi awọn eeyan ṣe oogun ti wa wọ pọ lawujọ.
Babalawo Idowu sọ pe ikanju lo bi gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii lati inu ile bọ si ode to fi de ọdọ ijọba.