Fadlullah Agboluaje: Ohun tí ó ṣokùnfà ikú Fadlullah Agboluaje, akẹ́kọ̀ọ́ tó kú sí Ukraine ní ọjọ́ kejì tó dé ibẹ̀

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà nílẹ̀ òkèrè (NIDCOM), ti ní èsì àyẹ̀wò òkú Fadlullah Adebayo Agboluaje ti fìdìí rẹ̀ múlẹ̀ pé àpọ̀jù òtútù ló pa á.

Ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kìíní, ọdún 2022 ni Fadlullah Agboluaje gúnlẹ̀ sí orílẹ̀ Ukraine tí wọ́n sì bá òkú rẹ̀ ní yàrá rẹ̀ ní ọjọ́ kejì tó dé bẹ̀.Kí ló pa akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàíjíríà tó kú lọ́jọ́ kejì tó dé ilé ẹ̀kọ́ ní Ukraine?

NIDCOM ní èsì àyẹ̀wò òkú Fadlullah Agboluaje ṣàfihàn pé òtútù ló pa á sínú yàrá.

Alága àjọ NIDCOM, Abike Dabiri-Erewa ṣe àbẹ̀wò sí mọ̀lẹ́bí ọmọ náà.

Àwọn mọ̀lẹ́bí Fadlullah ti ṣaájú fẹ̀sùn kàn aṣojú ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Lviv Polytechnic National University fún ìwà àìbìkíkà lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ kò ì tí ì kàn sí wa títí di òní:

Ìyá Fadlullah, Olaide Agboluaje ti ní kò sí ohun tí àwọn le ṣe lórí èsì àyẹ̀wò òkú ọmọ òun nítorí àwọn kò sí níbẹ̀.

Ó ní kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ọmọ òun yóò lọ sí ilẹ̀ òkèrè, tí àìsàn tàbí ààrùn kankan kò sì bá a jà kí ó tó lọ.

Nígbà tó ń bá ikọ̀ BBC sọ̀rọ̀, Olaide kọminú pé títí di àsìkò yìí ilé ẹ̀kọ́ náà kò ì tí ì kàn sí wọn láti bá wọn kẹ́dùn lórí ikú ọmọ náà.

"Mi ò gbọ́ nǹkankan láti ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, wọn ò tara rárá, ó yẹ kí wọ́n ó bá wa kẹ́dùn ṣùgbọ́n a ò gbọ́ láti ọ̀dọ wọn."

Bákan náà ló ní ó wu òun láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún ọmọ òun tí Ukraine yóò bá gba òun láyè láti yọjú síbi ìsìnkú rẹ̀.