Fadlullah Adebayo Death in Ukraine: Mọ̀lẹ́bí figbe ta pé ejò lọ́wọ́ nínú lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ tó kú lọ́jọ́ kejì tó dé ilé ẹ̀kọ́ nílẹ̀ òkèèrè

Se ni idunnu n subu lu ayọ fun idile Fadlullah Adebayo ni ọjọ kẹjọ osu Kinni ọdun yii nigba ti ọkunrin naa n tẹkọ leti l sorilẹede Ukraine lati lọ kawe si.

Koda, wọn sin de papakọ ofururfu nilu Eko, wọn rẹrin si ara wọn, ti wọn si juwọ sira pe o digba kan naa lai mọ pe o digbose titi aye ni fun ọkunrin naa, wọn ko tun foju kanra mọ.

Idi ni pe ọjọ keji ti Fadlullah Adebayo de sile ẹkọ to n lọ nilẹ Ukraine ni wọn tufọ iku rẹ fun awọn mọlẹbi rẹ pe o ti jade laye, to si ku sinu yara rẹ ni oru mọju.

Haa, oro o, iru kini eyi, bawo lo se jẹ ni awọn ibeere akọ to n jade lnu ẹbi akẹkọ naa, ti wọn si f mọ iru iku to mu olufẹ wọn lọ lairotẹlẹ ni wakati mejila to de ile ẹkọ to n lọ ni Ukraine.

Bawo ni isẹlẹ yii se waye?

Rofiat Agboluaje tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Fadlullah Adebayo tó kéde ikú àbúrò rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára tí kọminú lórí ikú òjijì tó já àbúrò rẹ̀ gbà lẹ́yìn ọjọ́ kejì tó dé orílẹ̀ èdè Ukraine láti lọ kàwé.

Gẹ́gẹ́ bí Rofiat ti wí, Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹjọ, oṣù kìíní, ọdún 2022 ni Fadlullah gbéra kúrò ní Nàìjíríà tó sì balẹ̀ sí Ukraine lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹsàn-án láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Lviv Polytechnic National University.

Ó ní "Títí di aago mọ́kànlá alẹ́ ọjọ́ Àìkú ọjọ́ kẹsàn-án mọ́júmọ́ ọjọ́ Ajé ọjọ́ kẹwàá, oṣù kìíní, ọdún 2022 ni màmá mi àti àbúrò mi ń sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀."

"Nígbà tó di àárọ̀ ọjọ́ Ajé tí a pe fóònù rẹ̀ kò gbe, kò fèsì sí àwọn àtẹ̀jíṣẹ́."

Kò nífẹ̀ẹ́ sí yàrá tí wọ́n fún un

Rofiat ni àbúrò òun kò nífẹ̀ẹ́ sí yàrá tí wọ́n fún un láti máa sùn gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yìn tí aṣojú ilé ẹ̀kọ́ náà wá pàdé rẹ̀ ní pápákọ̀ òfuurufú.

Aṣojú Lviv polytechnic National University ló wá pàdé àbúrò mi ní pápákọ̀ òfuurufú tó sì mu lọ sí yàrá rẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹsàn-án.

Nígbà tó dé yàrá náà, kò nífẹ̀ẹ́ sí rárá nítorí bí ibẹ̀ ṣe rí, màmá mi wá sọ fún un pé kí ó lọ bèèrè pé kí wọ́n ba pààrọ̀ rẹ̀.

Rofiat ṣàlàyé pé nígbà tó dé ibi tí yóò ti bèrè fún pípàrọ̀ yàrá, ó ri pé ẹni náà kò gbọ́ èdè gẹ̀ẹ́sì, èyí ló fà á tó fi pe alárinà ilé ẹ̀kọ́ náà tó orúkọ rẹ̀ ní orí ìwé tí wọ́n fi gbà á sí ilé ẹ̀kọ́.

"Ẹni náà sọ fún un pé kí ó ní sùúrù di aago méje ọjọ́ kejì.

" Nígbà tí a ń pe fóònù rẹ̀ ní ọjọ́ kejì tí kò gbé, màmá mì pe alárinà yìí ṣùgbọ́n tí kò gbé fóònù, tí a kò sì mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ tó gbé fóònù fún akẹ́kọ̀ọ́ kan láti túfọ̀ ikú àbúrò mi fún wa."

Ó fi kun pé àbúrò òun kò ṣe àárẹ̀ kò tó kúrò ní Nàìjíríà, orísìírísìí àyẹ̀wò ló sì ṣe, kódà tó fi mọ́ àyẹ̀wò COVID-19, tí gbogbo èsì àyẹ̀wò ni ó dáńgájíá.

Bákan náà ló ní ó ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19, ibà pọ́njúpọ́ntọ̀ kí ó tó kúrò ní ilé. Ó ní gágá lara rẹ̀ yá.

Ǹjẹ́ àjọ Nidcom mọ̀ sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí?

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó wà ní ilẹ̀ òkèrè, NIDCOM, sọ fún BBC pé àwọn ti gbọ́ sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí rẹ̀.

"Ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ náà, ó jẹ́ ohun ẹ̀dùn ọkàn fún wa pé a pàdánù ọmọkùnrin náà. Ìjọba máa tó gba ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ilé iṣẹ́ yìí.

Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Franca Omaluyi náà sọ fún BBC pé àwọn tí ń bá aṣojú ilẹ̀ Ukraine sọ̀rọ̀ lórí àdánù náà.

Ìwé ìpẹ̀jọ́ láti mọ kí ló pa Fadlullah

Lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, ènìyàn 2,525 ló ti buwọ́lu ìwé ìpẹ̀jọ́ láti mọ ohun tí ó ṣokùnfà ikú Fadlullah lẹ́yìn tí àwọn ẹbí rẹ̀ ń bèèrè fún ìbuwọ́lù ènìyàn 5,000 lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Màmá Fadlullah ní òun ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ rẹ̀ nítorí èyí ni òun ṣe buwọ́lu ìwé náà àti pé ọgbẹ́ ọkàn ni ikú ọmọ náà jẹ́ fún òun tó sì rọ àwọn ènìyàn láti buwọ́lu ìwé náà.