Àbúrò mi dágbéré pé òun fẹ́ dé ibì kan, ìròyìn ikú rẹ̀ ni mo gbọ́

Ẹgbọn ọmọbinrin ti iroyin sọ pe ọrẹkunrin rẹ ati awọn mẹta mii pa fun oogun owo, ti sọ pe iyalẹnu ni pe ọmọkunrin naa lo papa pa Rofiat.

Ọjọ Satide ni ọwọ ọlpaa tẹ awọn ọdmkunrin mẹrin ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ. nilu Abeokuta.

Nibi ti wọn ti n dana sun ori eeyan ni ọwọ ti tẹ wọn.

Arabinrin Okeowo sọ fun iwe iroyin Punch pe lẹyin ti aburo oun gbe ounjẹ alẹ kana ni ọjọ Ẹti, ọkọ kejidinlọgbọn, oṣu yii, lo tọrọ aaye lọwọ mi pe o n fẹ de ibi kan.

O sọ pe oun fun ni aaye, botilẹ jẹ pe ko sọ ibi to n lọ.

"Nigba to di bi aago mẹjọ aabọ alẹ, mo pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ lati beere pe ṣe o n pada bọ nile.

"Esi to fun mi ni pe oun ti wa ni ọna ile pada. Ni emi ba wọle sun."

"Nigba to tun di aago mẹwaa ti mi or i ko de, mo tun pe lori foonu ṣugbọn nọmba rẹ ko lọ mọ.

"Mo bi iya rẹ leere pe ṣe o ti ri ọmọ rẹ, o ni rara. Esi kan naa ni mo gbọ ni owurọ ọjọ keji."

Okeowo sọ pe ọjọ keji ni oun gbọ iroyin pe wọn pa ọmọbinrin kan ni adugbo wọn.

"Kia si ni ara fu mi nitori mi o gburo Rofiat titi di asiko naa."

O ṣalaye pe oun da ọkan ninu awọn ọmọkunrin ti aworan wọn wa lori ayelujara pe wọn bẹ ọmọbinrin naa lori mọ.

Eyi si lo jẹ ko mu aworan Rofiat lọ si agọ ọlọpaa ni adugbo Adatan, nibi ti DPO ti sọ fun pe wọn ti pa aburo rẹ.

O ni lati igba ti awọn ti kilọ fun ọrẹkunrin Rofiat pe ko gbọdọ wa a wa mọ, ni oun ko ti ri ọmọkunrin naa.

"Nitori naa lo ṣe yamilẹnu pe oun oun lo pa aburo mi."

Lati bi ọjọ melo kan ni iroyin bi awọn ọdọ sẹ n gbiyanju lati fi eniyan ṣe oogun owo ti n gbalẹ ni Naijiria, eyi to si ti n kọ ọpọlọpọ eeyan lomiinu lawujọ.

Bi ọwọ ọlpaa ṣe tẹ awọn afurasi naa

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti mu ọdọmọkunrin mẹta ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ fun ẹsun pe wọn pa ọrẹbinrin rẹ wọn kan fi sẹ oogun owo.

Awọn meji ko ti i pe ogun ọdun, nigba ti ọkan ti pe.

Awọn afurasi naa ni Wariz Oladeinde, Abdulgafar Lukman, ati Mustakeem Balogun.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe owurọ kutu ọjọ Satide, ọjọ kọkandinlogun, ọdun yii ni ọwọ tẹ wọn lẹyin ti olori ẹṣọ alaabo adugbo Oke Aregba, nilu Abeokuta, fi ẹjọ sun ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ pe iroyin to tẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni Adatan leti ni pe awọn afurasi naa n dana sun nkankan ninu ikoko, eyi ti Ọgbẹni Segun Adewusi fura si pe ori eeyan ni.

Lẹyin eyi ni ọga ọlọpaa ni Adatan, SP Abiodun Salau, ati awọn ọlọpaa kan lọ si agbegbe naa nibi ti ọwọ ti tẹ awọn afurasi ọhun.

Ẹnikẹrin wọn to ni ọrẹbinrin ti wọn pa kọkọ salọ, ṣugbọn ọwọ pada tẹ ẹ.

Kinni awọn afurasi ọdọ naa sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa?

Gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Trust ṣe sọ, lẹyin ifọrọwanilẹnuwo ni ileeṣẹ ọlọpaa, ni awọn afurasi naa jẹwọ pe ori ọrẹbinrin ọrẹ awọn to salọ ni awọn n dana sun ninu ikoko.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ọmọkunrin naa jẹwọ pe ọrẹkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Soliu lo fi ẹ̀tàn tan ọmọbinrin naa, Rofiat, wa sibi ti awọn mẹrẹẹrin ti pa a

Lẹyin naa ni wọn ge ori rẹ, ti wọn si ko ẹran ara rẹ yooku sinu apo kan ti wọn ju sọnu si ile atijọ kan.

Awọn afurasi ọhun mu awọn ọlọpaa de ile naa, nibi ti wọn ti ri iyoku ara ọmọbinrin ọhun ninu apo.

Bakan naa ni wọn tun ba àdá kekere kan ati ọ̀bẹ ti awọn afurasi ọhun fi ge ori rẹ.

Ni bayii, wọn ti gbe oku Rofiat lọ si mọṣuari ileewosan gbogboogbo fun ayẹwo.

Kọmisaana ọlọpaa si ti paṣẹ pe ki ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n wadi iru awọn ẹsun bẹẹ bẹrẹ iwadii , pẹlu eto bi awọn afurasi yoo ṣe di eero ile ẹjọ.

Iru iroyin yii kii ṣe tuntun ni orilẹ-ede Naijiria.

Ọsẹ meji sẹyin ni ọwọ tẹ ọdọmọkunrin mẹta ti ọjọ ori wọn jẹ mẹẹdogun nilu Sagbama, to wa ni ipinlẹ Bayelsa, nibi ti wọn ti n gbiyuanju lati fi ọmọbinrin kan sẹ oogun owo.

Gẹgẹ bí àwọn araadugbo ṣe wi, awọn afurasí wọn yi ti n peelo ati fi ẹni yi ṣe oogun owo ki awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ati awọn ọdọ adugbo naa to mu wọn.

Iwadii fi hàn pé àwọn atilaawi yi ti pa iyè Comfort rẹ, ti wọn sì ni kí o tẹle awọn lọ sí ile ọkan ninu wọn, Emomotimi Magbisa.

Nigba ti wọn dé ọdọ rẹ, wọn ge ika rẹ ti wọn sì fọn ẹjẹ rẹ soju gilaasi kan.