You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Students attack Police: Ìjà ní DPO wà parí láàrín àwọn akẹ́kòó ilé ẹ̀kọ́ gírámà kí wọn tó fí oko fọ lórí
Ọga DPO agọ ọlọpaa to wa ni Obantoko si Adatan nilu Abeokuta, nipinlẹ Ogun ti ri iya he lọwọ awọn akẹkọọ ile iwe girama meji kan to wa ni Abeokuta.
Ninu iroyin to tẹ wa lọwọ, SP Alimeke Ignatius ati awọn ọmọ isẹ rẹ la gbọ pe awọn akẹkọọ yii doju ija kọ lasiko tawọn akẹkọọ Egba Comprehensive High School ati Asero High School fija pẹẹta.
Awọn ọlọpaa agọ Obantoko la gbọ pe wọn lọ pẹtu si ija to n waye laarin awọn akẹkọọ girama ọhun, ko to di pe awọn naa fara kaasa iya lọdọ awọn akẹkọọ ọhun.
- Èròngbà ìjọba Naijiria lórí yíyọ 'subsidy' rújú, a kò fara mọ̀-NLC
- Ibùdó àṣà Yorùbá lágbàyéé gbọ́dọ̀ ṣètò báwọn nkan ìṣẹ̀mbáyé wa yóò ṣe padà láti òkè òkun - Osinbajo
- "Akẹ́kọ̀ọ́ 1,440 ní iléẹ̀kọ́ 25 ni àwọn agbébọn ti jígbè lọ ní Naijiria"
- Àlàyé ọlọ́pàá Osun rèé lórí ọ̀nà tí Rahmon Adedoyin gbà ká ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínu fọ́nrán ohùn tó lu ayélujára pa
- Femi Fani-Kayode ṣàlàyé bí ìrìnàjò rẹ̀ sọ́dọ̀ EFCC ṣe jẹ́
- Kọmísánà ọlọ́pàá tú àṣírí bí ọmọ Rahmon Adedoyin ṣe ju òkú Timothy Adegoke sígbó, tó na pápá bora
- Ìjọba Eko fi ọwọ́ ọlà gbá ìyá Jumoke lójú ní ₦1m àti ilé tó hááyà fún - Agbẹjọ́rò
Gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti se fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba, awọn akẹkọọ yii n lẹ oko mọ ara wọn, ti wọn si di oju ọna pa eyi to fa iporuru ọkan fun ara adugbo.
O ni Alimeke ati awọn ikọ rẹ to lọ sibẹ lati da alaafia pada lawọ́n akẹkọọ naa se lese.
Oyeyemi ni ''oko ba DPO. Nise ni awọn akẹkọọ yii n lẹko, ti wọn si n ju nkan ija oloro lasiko ikọlu naa''
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ boya wọn mu awọn akẹkọọ naa, o sọ pe ''awọn ko le mu awọn akẹkọọ nitori ọjọ ori wọn si kere.
A kan le fi wọn si ahamọ fun igba diẹ, ka si gba wọn nimọran ti a o si tu wọn silẹ lẹyin naa''
Ẹwẹ, ẹka igbimọ araalu ati awọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun (PCRP) ti sapejuwe isẹlẹ yii gẹgẹ bii eleyi to ''tako laakaye, ti ko si nidi''
Alaga ẹgbẹ PCRP Samson Kunle Popoola sọ ninu atẹjade kan pe ''bi wọn ko ba tete wa nkan se si iru iwa bayi, o lewu pupọ fun ọjọ ọla orileede yii''
Iwa ka maa se ikọlu si olukọ tabi ẹlomiran lati ọwọ awọn akẹkọọ kan, ti fẹ gbode ni ipinlẹ Ogun lẹnu ọjọ mẹta yi.
Bi a ko ba gbagbe, awọn akẹkọọ ipinlẹ yii kanna la gbọ pe wọn da sẹria fawọn olukọ to n ba wọn wi lori iwa to tako ofin ile ẹkọ.
Bẹẹ naa ni a gbọ pe kiko ẹgbẹkẹgbẹ ko jẹ tuntun mọ fawọn akẹkọọ yii, ti omiran ninu wọn si wa ninu ẹgbẹ okunkun.
Sugbọn sa, ijọba ipinlẹ Ogun oun ti n mojuto isẹlẹ yii nipa pe ki awọn olukọ kọkọ dawọ lilu awọn akẹkọọ duro lọna ibawi.