You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Subsidy Removal: NLC, ilé aṣòfin àgbà Naijiria àti àwọn mìíràn tako èròngbà ìjọba àpapọ láti yọ subsidy
Ẹgbẹ osisẹ lorileede Naijiria ti tapa si erongba ijọba Naijiria lati yọ ẹdinwo to wa lori owo bẹntiroo.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita l'Ọjọru eyi ti aarẹ Ayuba Wabba fọwọ si, ni ẹgbẹ ti osisẹ sapejuwe igbesẹ yi gẹgẹ bi eleyi to ruju.
Wabba sọ pe ọrọ naa dabi ẹni pe ijọba fẹ fi ọwọ ọtun fun araalu ni nkan ki o si fọwọ osi gba pada.
Bẹẹ naa ni wọn se apejuwe rẹ gẹgẹ bi ipalẹmọ fun ọwọngogo ọja eleyi ti ipa ko ni ka.
Ninu atẹjade taa n wi yi ti wọn pe akọle rẹ ni ''Awa osisẹ kọ lati ko si panpẹ yi'' ẹgbẹ NLC sọ pe ''erongba ijọba lati fikun owo epo lọna igba le ju ti tẹlẹ lọ yoo mu alekun ba owo ọja ni Naijiria''
- Ọdún tó ń bọ̀ ni okọ̀ òfúrufú ‘Air Nigeria’ yóò gbérasọ
- Ẹ màá múra sílẹ̀ láti ra lítà epo kan ní ₦320 sí ₦340 lọ́dún 2022- NNPC
- Jàndùkú kọlù mi, gé mi lára bíi olè torí mo jẹ́rìí tako ìjọba níbi ìwádìí ìpànìyàn Endsars Lekki''
- Kò sí ìfẹ̀míṣòfò kankan ní Lekki Too Gate, àlọ́ àpamọ̀ lásán ni èsì ìgbìmọ̀ EndSARS - Lai Mohammed
Ẹgbẹ NLC tẹsiwaju pe yoo silẹkun fun wahala orisirisi ti yoo se alekun awọn ipenija bi aabo to wa nilẹ to si le mu ki awọn araalu ṣe iwọde tako ijọba.
"Eleyi kii se ohun ti ọmọ Naijiria kankan n gbero rara ati rara.''
Wabba sọ pe ijọba apapọ ati banki agbaye kan n da ijiroro se laarin awọn ni .
O ni idi ni pe awọn ko ni sinmi lati tako ilana eto ọrọ aje ti wọn fẹ gunlẹ eleyi ti o rọ mọ gbigbe ọja wọle lati ilẹ okere nikan.
Aarẹ ẹgbẹ osisẹ sọ pe yoo soro lati jẹ ki araalu gbagbọ idi ti Naijiria to wa lara ẹgbẹ awọn orileede to n ta epo lagbaye ko ni le da epo rọbi pọn fun ara rẹ.
Yatọ si eleyi, Wabba tun bẹnu atẹ lu owo irọrun ẹgbẹrun marun un Naira ti ijọba ni oun yoo san fun ogoji miliọnu ọmọ Naijiria gẹgẹ bi owo irina.
O ni kii se gbogbo eeyan ni yoo ri owo naa gba, bẹ si ni ile asofin agba Naijiria naa ni nkan ti wọn sọ lori rẹ.
Lọjọru yi kanna, alaga igbimọ to n risi eto inawo nile asofin agba, Sẹnetọ Solomon Adeola sọ fawọn oniroyin pe ko si ipese fun owo ẹgbẹrun marun un ti ijọba fẹ fun ogoji miliọnu araalu ninu aba isuna ọsun 2022 to wa niwaju ile.
O ni ijọba apapọ yoo ni lati gbe aba pe awọn fẹ na owo yi wa siwaju ile kawọn baa le buwọlu ko ti pe o di ofin.
O ni ko si bi ijọba apapọ yoo se danikan gbe igbesẹ eto inawo triliọnu meji Naira lae se pe ile asofin mọ si.
- Tówẹ́ẹ̀lì ni bàbá mi ró mọ́ ìdí nígbà tí àwọn sọ́jà wọlé mu lọ - Ọmọ Akintunde
- Jàndùkú kọlù mi, gé mi lára bíi olè torí mo jẹ́rìí tako ìjọba níbi ìwádìí ìpànìyàn Endsars Lekki''
- Femi Fani-Kayode ṣàlàyé bí ìrìnàjò rẹ̀ sọ́dọ̀ EFCC ṣe jẹ́
- Ẹ lọ san ₦20bn owó ìtanràn fún Sunday Igboho títí January - Iléejọ́ fọnmú fún DSS
Asofin naa tun bẹnu atẹ lu ilana ti ijọba fẹ fi mọ awọn ti iru owo iranwọ lilọ bibọ yi yoo tọ si.
Awọn asofin nikan kọ lo sọ si ọrọ yi, awọn ọmọ ẹgbẹ osisẹ lẹka ilera JOHESU naa ti ni ki ijọba fi ẹlẹ se lori erongba lati yọ ''subsidy'' to wa lori bẹntiroo.
Amọ sa Minisita feto inawo,isuna ati eto Zainab Ahmed ti tun mu alaye bọ ẹnu lori idi ti wọn fi fẹ yọ ẹdinwo to wa lori owo bẹntiroo.
Lẹyin ipade igbimọ alasẹ ijọba apapọ lo fi ọrọ yi to awọn akọroyin leti.
Ahmed sọ pe pẹlu bi ileesẹ to n risi pipọn epo ni Naijiria NNPC ko se ri owo kankan san si akoto ijọba apapọ mọ, ijọba apapọ ko ni le maa san owo ẹdinwo subsidy ojilenigba le mẹwaa tawọn n san losoosu.