You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EndSARS: Lai Mohammed ní ìjọba kò ní gba èsì ìgbìms náà wọlé nítorí ó tako ẹ̀rí tó wà nílẹ̀
Ijọba apapọ ti fesi si abajade iwadii igbimọ to ṣe iwadii ikọlu awọn ọmọ ogun si awọn oluwọde EndSARS ni iloro Lekki Toll Gate to wa niluu Eko.
Minisita eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammaed sọ nibi ipade awọn akọroyi kan to waye l'Abuja pe alọ apamọ lasan ni abajade iwadii igbimọ naa, ati pe ijọba apapọ ko le gba abajade naa wọle.
Lai sọ pe "A kọ lati gba pe awọn ọmọ ogun wa fi ẹmi awọn ọmọ Naijiria ṣofo ni iloro lekki Toll Gate logunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020."
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Ọmọbíbí Rahmon Adedoyin tó ni ilé ìtura tí Timothy Adegoke kú sí, ló jù òkú rẹ̀ sígbó - Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Osun
- Àìsí Atúmọ̀ èdè Yorùbá sí Gẹ̀ẹ́sì pagidínà ìgbẹ́jọ́ ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho méjì
- Naijiria yóò dojúrú tí Buhari bá tú Nnamdi Kanu sílẹ̀ - Ẹgbẹ́ àpapọ̀ l‘Ókè Ọya
- Afurasí ológun gbé alága NURTW tẹ́lẹ̀ l‘Oyo pé ó ń ṣe onígbọ̀wọ́ Sunday Igboho
- "Buhari, Sanwo-Olu, ẹ kọ̀wé fipò sílẹ̀ torí àwọn ọ̀dọ́ tó kú lásìkò ìwọ́de EndSARS"
- Buhari, fi Sunday Igboho sílẹ̀, kí ìṣọ̀kan le padà sí Naijiria - Oluwo
"Eredi ni pe abajade iwadii igbimọ naa tako awọn ẹri to wa nilẹ."
Minisita naa ni ohun to lagbara ni ẹsun ipaniyan jẹ, kii sii ṣe eyii ti awọn igbimọ naa le kede lai si ẹri to fẹsẹ mulẹ, ati pe esi iwadii igbimọ naa mọọmọ fẹ doju ti ijọba apapọ ni.
O ni "Ijọba apapọ ko faye gba awọn agbofinro lati maa fi iya jẹ awọn araalu lai nidi, idi ree ti a ṣe tu ẹka ileeṣẹ ọlọpaa SARS ka, ti a si ni ki awọn ipinlẹ gbe igbimọ didie lati ṣe iwadii awọn oṣiṣẹ ẹka naa."
Ṣaaju ni abajade iwadii igbimọ ọhun ti kọkọ lu jade, eyii to sọ pe awọn ọmọ ogun mọọmọ fi ẹmi awọn oluwọde ṣofo lọjọ naa lọhun.
Awọn nnkan mii ti Lai Mohammed sọ ree
- Abajade naa ko sọ nipa ẹri awọn onimọ nipa ibọn ati ohun ija oloro
- Igbimọ naa tako ara rẹ lẹyin to sọ pe eeyan mọkanla lo ba iṣẹlẹ naa lọ nigba to ti kọkọ sọ ṣaaju pe awọn ṣe ayẹwo iku to pa eeyan mẹta pere nibi iwọde naa
- Igbimọ naa gba ẹri okunrin kan to sọ pe oun ka oku mọkanla nibi iwọde naa. To ba pe jẹ lootọ lo wa ni ẹsẹ kan ati ẹsẹ kan ọrun, bawo ni o ṣe ri aye maa ka iye oku to wa nilẹ.
- Igbimọ ọhun ni awọn ọmọ ogun gbe ọkọ wa lati ko oku awọn eeyan ati lati fọ iloro Lekki Toll gate naa mọ, amọ awọn ṣi ri ọta ibọn lagbegbe ọhun lẹyin ọjọ mẹwaa ti iṣẹlẹ naa waye
- Igbimọ naa sọ pe awọn pa awọn eeyan nibi nibi iwọde ọhun, ṣugbọn ko si ẹbi kankan to yọju sita pe awọn n wa oku mọlẹbi wọn to ku nibi iwọde naa
- Okunrin kan sọ pe fun igbimọ naa pe oun ri oku arakunrin oun ni Lekki Toll gate ṣugbọn orukọ okunrin yii kan naa wa lara orukọ awọn oku ti igbimọ naa fi lede
- Igbimọ naa ko sọrọ nipa awọn ọlọpaa atawọn ọmọ ogun to ku lasiko iwọde ọhun
- O tun sọ pe abajade iwadii naa ko mẹnuba ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn oniṣowo ti wọn padanu owo gọbọi lasiko iwaọde naa