You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bola Tinubu: N kò rán ẹnikẹ́ni láti bẹ̀rẹ̀ ìpolongo fún ìbò ààrẹ ọdún 2023
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti fesi si iroyin to tan kalẹ lori ayelujara pe o ti ṣe agbekalẹ ohun ti yoo fi ṣe ipolongo fun ibo aarẹ ọdun 2023.
Oluranlọwọ lori ọrọ iroyin si Tinubu, Ọgbẹni Tunde Rahman lo sisọ loju ọrọ yii fun BBC Yoruba, to si ni iroyin ofege lasan ni.
Ọgbẹni Rahman ṣalaye pe o digba ti Tinubu ba to kede erongba rẹ lati dupo aarẹ, ki o to le sọ nipa ipolongo ibo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kọmísánà ọlọ́pàá tú àṣírí bí ọmọ Rahmon Adedoyin ṣe ju òkú Timothy Adegoke sígbó, tó na pápá bora
- Wọ́n ní ajé wà lárá ọkọ mi ní wọ́n ṣe lò ó - Opó Timothy Adegoke gbarata
- Ẹ lọ san ₦20bn owó ìtanràn fún Sunday Igboho títí January - Iléejọ́ fọnmú fún DSS
- Ṣé lóòtọ́ ni àjọ EFCC mú Femi Fani-Kayode?
- Kò sí ìfẹ̀míṣòfò kankan ní Lekki Too Gate, àlọ́ àpamọ̀ lásán ni èsì ìgbìmọ̀ EndSARS - Lai Mohammed
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- Bí àyẹ̀wò òkú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU tó kú sílé ìtura, ṣe wáyé rèé
- Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho méjì síwájú torí kò sí atúmọ̀ èdè Yorùbá
- Ìjọba Eko fi ọwọ́ ọlà gbá ìyá Jumoke lójú ní ₦1m àti ilé tó hááyà fún - Agbẹjọ́rò
''Ko si ohun to jọọ pe Tinubu ti ṣe agbekalẹ eto ipolongo fun ibo aarẹ ọdun 2023, Asiwaju ko tii kede pe oun yoo dije ninu ibo aarẹ to n bọ lọdun 2023.
Awọn oriṣiiriṣii ẹgbẹ awọn ololufẹ Tinubu lo wa nidi ọrọ iroyin ipolongo fun ibo aarẹ orilẹede Naijiria to wa lori ayelujara.
Asiwaju ko mọ ohun kan ni pa rẹ, bakan naa ni ko mọ ohunkohun nipa awọn eeyan to n ha raisi ati ẹwa ninu baagi kaakiri.
Awọn afẹnifere ti wọn nifẹ Asiwaju lo n ṣe awọn nnkan yii fawọn eeyan, Asiwaju ko ran ẹnikan ni iṣẹ, ko si fun ẹnikan kan lowo lati maa pin raisi tabi ẹwa.
A o le da awọn eeyan yii lọwọ kọ nitori itọrẹ aanu ni wọn n ṣe fawọn ti ko rọwọ họri lawujọ.
Asiko kan tiẹ wa ti Asiwaju ni lati dupẹ lọwọ awọn eeyan yii fun iṣẹ itọrẹ aanu ti wọn n ṣe fawọn eeyan.
O ti pẹ ti awọn eeyan yii ti n ṣe awọn ohun ti wọn n ṣe ni orukọ Tinubu bo tilẹ jẹ p e ko mọ nipa rẹ,'' Ọgbẹni Rahman lo ṣalaye bẹẹ.
Oriṣiiriṣii nkan bii aṣọ ilewọ, fila, ounjẹ inu baagi lawọn eeyan kan n pin eleyii ti orukọ Tinubu fun ipo aarẹ ọdun 2023 wa lara rẹ.