Yoruba World Centre:: Osinbajo àtàwọn àgbà Yorùbá ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ibùdó àṣà Yorùbá lágbàyéé

Igbakeji Aarẹ Naijiria, Yemi Osinbajo ti rọ awọn alamojuto ibudo Yoruba l'agbaye, Yoruba World Centre (YWC) lati ṣe agbatẹru bi awọn nkan iṣẹmbaye Yoruba ti awọn kan jigbe tabi ko kuro ni ilẹ Yoruba lọna ti ko ba ofin mu, yoo ṣe jẹ dida pada.

Nibi ayẹyẹ ifilọlẹ Ibudo Aṣa ati nkan abalaye Yoruba, International Centre for Yoruba Arts and Culture (INCEYAC) to waye ni Fasiti Ibadan, ni Osinbajo ti sọ ọrọ naa lọjọ Iṣẹgun.

Osinbajo sọ pe ibudo INCEYAC "gbọdọ darapọ mọ igbesẹ to n lọ ni agbaye lati da awọn nkan iṣẹmbaye naa pada si ilẹ yii.

Koda, ibudo yii le jẹ ibi isinmi fun awọn nkan iṣẹmbaye ti wọn ba da pada, amọ ti ibi ti wọn ti gbe e ko ba tete jẹ mimọ,"

Ẹni to ṣe agbatẹru ibudo tuntun naa, Alao Adedayo sọ pe ọdun 2014 ni oun ti bẹrẹ iṣẹ lori rẹ, pẹlu erongba lati da ibudo kan silẹ nibi ti awọn onimọ le lọ lati ṣe iwadii nipa ìtàn, àṣà ati awọn nkan iṣẹ ọna nilẹ Yoruba.

Lara awọn to peju sibi ayẹyẹ naa ni Alaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi, Gomina ipinlẹ Ooy, Ogun ati Osun, botilẹ jẹ pe awọn igbakeji wọn lo ṣoju wọn.

Wọn si rọ awọn alakoso ibudo naa pe ki wọn o ma a jẹ abuku ba akọsilẹ itan tabi ki ọrọ oṣelu bọ iṣẹ wọn.

Bakan naa ni Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams naa wa nibẹ.