You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Murphy Afolabi: Kò dùn mí tí wọn bá ṣe yẹ̀yẹ́ mi torí mò ǹ fi sí pe ṣí, èdè Osogbo ìlú mi ni
Ori lo mọ isẹ asela, ibi ti ori wa si n lọ, agba adura ni pe ki ẹsẹ sin wa de ibẹ.
Bẹẹ lo ri fun gbajumọ osere tiata kan, Murphy Afolabi Olawale, ẹni ti isẹ tiata ti wu lati kekere, ti kii si se ayaba fun.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Murphy Afolabi ni oun ko lọ sile ẹkọ girama amọ oun kẹkọọ jade nile ẹkọ fasiti Eko bi o tilẹ jẹ pe awọn onijibiti ti gba oun kọja sisọ ninu iyanju oun lati wọ awọn fasiti kan tẹlẹ.
Osere tiata naa ni Araba awo tilu Osogbo, oloye Ifayemi Elebuibon, tii se baba fun oun lo se koriya fun oun lati yan isẹ tiata laayo.
- Mo kan sara sawọn ayasọlo- Dayo Amusa
- Ki ní yóò sẹlẹ̀ sí Àrẹ́mọ Ooni Ile-Ife tí wọ́n bá gbé e kúrò l'Áàfin?
- Yekeen Ajileye, ọ̀gá mi nínú iṣẹ́ tíátà ṣẹ̀ mí, ó ṣẹ ẹlẹ́dàá mi - Abija
- Bí mó bá fojú kan Baba Wande lórí ìtàgé, ṣe ní ẹ̀rù máa ń bà mí - Tafa Oloyede
- Iṣẹ́ ọpọlọ ló yẹ ká ṣe nínú tíátà, kìí ṣe àfihàn ara bíbó àbí ìhòòhò wa - Binta Mọgaji
- Àwọn òṣèré Nollywood tí wọn ò sí lóri amóhùmáwòrán mọ́
- Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Bàbá mi máa ń sunkún torí bí kò ṣe le padà ṣeré tíátà mọ́ - Ọmọ Baba Suwe
Nigba to n sọ awọn ipenija to ni nidi isẹ tiata, Murphy Afolabi Olawale ni oun gbe apoti asọ baba oun fun ọga oun lati sere tiata ni ogun ba de.
O wa salaye pe kii dun oun tawọn eeyan ba n fi oun se yẹyẹ pe oun maa n sọ ede ilu oke, ti oun si n fi si pe ṣi.
Gbajumọ osere naa fikun pe ede ilu Osogbo ti oun gbe dagba, ni oun n sọ, yoo si nira puọ lati paarọ ahọn oun nigba ti oun de Eko.
O wa yan pe awọn osere tiata to fi ere itage bẹrẹ isẹ bii ti oun ni akọsẹmọsẹ, yatọ si awọn osere aye ode oni ti wọn n gbe ẹrọ ayaworan lasan si loju.