Timothy Adegoke: Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn kò ṣègbè lẹ́yìn Adedoyin tó ni ilé ìtura Hilton, ti akẹ́kọ̀ọ́ OAU kú sí

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti ṣalaye pe Ọmọba Rahman Adedoyin, to jẹ ọkan lara awọn afurasi lori iṣekupani akẹkọọ fasiti OAU, Timothy Adegoke, ti ka fọnran ohun rẹ to lu oju ayelujara pa silẹ, ki awọn ọlọpaa to mu un.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Yemisi Opalola lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin.

Opalola ni fọnran ti ọkunrin naa sọrọ ninu rẹ pe, oun ko mọwọ mẹsẹ ninu ibi wn se pa Adegoke tabuku ileeṣẹ ọlọpaa tori ọpọ eeyan ro pe ni akata ọlọpaa lo ti sọrọ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni iṣẹlẹ yii gan an ti jẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa tubọ jara mọ iwadii ti wọn n ṣe lori awọn to ṣeku pa Adegoke.

Opalola ni ''afurasi Adedoyin sọ fun awa ọlọpaa pe oun sọrọ ninu fọnran nigba ti awọn ọlọpaa bẹrẹ si ni ko awọn oṣiṣẹ oun ni ile itura Hilton ni Ile Ife.

O ni oun ti sọrọ sinu fọnran yii ki awọn ọlọpaa to mu oun, ati pe oun ṣalaye ninu fọnran yii lati le jẹ kawọn eeyan ti wọn n pe oun ni oloogun owo mọ pe oun ko lọwọ ninu iku Adegoke.

O ni awọn eeyan ti sọ oun ni orukọ ti oun kii jẹ lai fi oju ofin wo ọrọ naa.

Ọjọ kọkanla ati ikejila oṣu kọkanla ni ileeṣẹ ọlọpaa mu awọn oṣiṣẹ Adedoyin nigba ti oun gan an dero agọ ọlọpaa lọjọ kẹẹdogun.

O ni oun ko tiẹ mọ pe fọnran naa ti lu ori ayelujara pa ki awọn ọlọpaa to sọ fun oun.

Adedoyin tiẹ tun sọ fun awa ọlọpaa pe foonu oun gan an ko si lọwọ oun mọ.''

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa wa ni awọn ko ni da isẹ duro lori ati tu iṣu de isalẹ koko lori iṣẹlẹ ọhun.

Opalola tun ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa ko figba kankan sẹgbe lẹyin Adedoyin.