Helen Paul: Orí ló yọ mi, mo ní ìjàmbá ọkọ̀ tó fa ìpalára fún orí àti ojú mi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja apanilẹrin, Helen Paul ti salaye idi to se n lo awo lati fi bo oju rẹ lẹnu lọọlọ yii.

Ninu ọrọ to kọ si oju opo Instagram rẹ lati kede iroyin naa, Helen Paul sọ pe ijamba nla kan oun ni nilu Abuja eyi to se akoba fun ẹyin oju ati ori oun.

O ni lasiko ti ijamba naa waye, se ni ori oun wu debi pe oun n fi gilaasi oju bo aṣiri apa to wa nibi ẹyinju naa ni.

O ni ọpọ igba ti oun ba ya aworan pẹlu awọn eniyan lasiko naa, ni oun kii yọ gilaasi naa, ti awọn kan si lero pe igberaga lo n mu ki oun ṣe bẹẹ.

O ni amọ wọn ko mọ nkan ti oun n la kọja, kii si se akọ sise tabi igberaga lo sun oun de idi lilo awo oju rara.

Apanilẹrin naa sọ pe ọpọ eeyan lo n fi nkan pamọ, to si jẹ pe iṣẹlẹ to ba dara nipa wọn nikan ni wọn n fihan araye lori ayelujara.

Amọ sa, ọpọ awọn ololufẹ rẹ to ka ikede yii lo n ba Helen Paul se ẹfẹ pe ko sọ tootọ boya wọn gba ni ẹsẹ loju ni oju rẹ se daranjẹ to bẹẹ.