You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho: Agbẹjọ́rò Igboho àti Aráàlú kan ní Benin figbe ta pé àìsàn rẹ̀ ń le si, ó nílò àdúrà
Awọn eeyan kan lorilẹ-ede Benin Republic ti ke gbajare si ijọba ilẹ naa lati fi oloye Sunday Igboho silẹ ko lọ tọju ara rẹ nilẹ okeere nitori ara ko ya, aisan naa si lagbara gidi.
Ọkan lara awọn eeyan naa, Agbomola Ajirotutu lo sọ ọrọ naa ninu fidio kan to fi lede lori ayelujara.
Ninu fidio ọhun lo ti ke sita pe oloye Sunday Igboho ko gbadun, o si yẹ ki awọn alẹnulọrọ ni Benin Republic da si ọrọ naa ki ijọba ilẹ ọhun le jọwọ rẹ lati lọ tọju ara rẹ ko ma baa ku silẹ awọn.
- Irú àìsàn wo ló ń bá Sunday Igboho finra ní Benin kí sì ní àwọn àgbààgbà Yorùbá n sọ sí ọ́rọ́ yi?
- Sunday Igboho, àwa Yoruba Nation kò gbàgbé rẹ sí àhámọ - Akintoye
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba orílẹ̀-èdè Benin ti gba ibọ̀dè lórí ẹjọ́ Sunday Igboho?
- Gómìnà Yoruba, ẹ dúró lé ìjọba àpapọ̀ lọ́rùn pé kó fi Sunday Igboho sílẹ̀ - Gani Adams
- Wo ìtàn ayé Sunday Igboho, gbajúmọ̀ ajìjàgbara fún ilẹ̀ Yorùbá
O ni "Ẹyin olowo ati ọlọrọ orilẹ-ede Benin ti ẹ gbọ Yoruba, gbogbo wa la mọ pẹ wọn mu oloye Sunday Igboho to jẹ ọmọ Naijiria si atimọle lorilẹ-ede wa nitori o fẹ gba orilẹ-ede wa kọja lọ silẹ mii."
"Ara rẹ ko ya bayii, aisan naa si lagbara gidi... Ẹyin gbajumọ ati ọlọrọ Benin, ẹ ẹ sì dahun si ki wọn gbe ọrọ yii kuro lẹyinkule wa nitori nkankan ko gbọ ṣe baba yii ni orilẹ-ede wa."
Ajirọtutu tẹsiwaju pe "Ẹ dide ki ẹ sọrọ soke ki wọn fi ọkunrin yii silẹ ko maa ba ti ẹ lọ, nitori ko si ohun to kan wa ninu ọrọ wọn."
Ọkunrin ọhun sọ siwaju si pe o ṣeeṣe ki gudugbẹ ja ni Benin Republic, ti Igboho le ba ku si orilẹ-ede naa.
O tun rọ awọn ọmọ ilẹ ọhun lati tẹ mọ ijọba ilẹ naa leti pe ko fi Igboho silẹ nitori ti ajijagbara naa ba le dakẹ silẹ awọn, awọn ọmọ ilu naa ni yoo fori fa rogbodiyan to ba ti ẹyin rẹ jade.
Lẹyin naa lo ni alaafia lo ṣe koko ati pe ẹmi ko laarọ, o ni o yẹ ki wọn jẹ ki Igboho tọju ara rẹ ki wọn to tẹsiwaju ninu igbẹjọ rẹ.
Amofin Yomi Aliyu ní igbẹ́yin Sunday Igboho ko gbọ̀dọ̀ da bi ti Busari Adelakun, ko si gbọ̀dọ̀ ku
Ẹwẹ, ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho to wa ni Naijiria, Yomi Aliyu naa tun fidi ọrọ naa mulẹ lori ikanni WhasApp rẹ, eyii ti BBC Yoruba foju ganni pe lootọ ni Igboho ti wa nile iwosan.
Aliyu ni "Oloye Sunday Igboho n ṣaisan gidi, o si ti wa nile iwosan bayii."
"Ẹ jọwọ ẹ ba wa fi adura ranṣẹ si, ki igbẹyin rẹ ma baa da bii ti Oloye Adelakun Eruobodo, Igboho ko gbọdọ ku o!."
- Ẹ dẹ́kun fífún ọkùnrin tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ní ìbálòpọ̀
- Akúṣẹ́ apẹja bọ́ sínú agbami ọrọ̀ lẹ́yìn tó rí èébì ẹja Wéèlì létíkun
- Ààrẹ Buhari sàlàyé ọdún tí wọn yóò parí òpópónà Eko si Ibadan
- Ìdí rèé tí ń kò fi máa lo bàálù àdáni - Oluwo
- Seyi Makinde pe olóyè PDP lẹ́jọ̀ fún ìbanilórúkọ jẹ́ lórí Facebook
- Buhari, ohun ìjà tó ń kójọ ni wọn yóò lò láti rẹ́yìn Nàíjíríà - Fr Mbaka
- "Èmi ni mo sọ fáwọn ọ̀gá ilé Keu pé kí wọ́n lu ọmọ mi bí ẹran"
- Ọlọ́run nìkan ló ni ẹ̀mí mi, ara mi ti le koko - Bola Tinubu