You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seyi Makinde Vs Ismaila Ashipa: PDP Oyo ní òun wà lẹ́yìn gómìnà láti gbé ọmọ ẹgbẹ́ relé ẹjọ́
Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde, ti wọ ọkan lara awọn oloye, to tun jẹ adari igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) nipinlẹ Oyo, Ismaila Ashipa lọ sile ẹjọ, fun pe o kọ nkan to ba gomina ni orukọ jẹ.
Ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 ni iroyin sọ pe Ashipa kọ ọ si oju opo Facebook rẹ pe Gomina Makinde gba iṣẹ lọwọ agbabọọlu ikọ Shooting Stars, Abubakar Adeyemi.
Ninu ọrọ naa to pe akọle rẹ ni 'GSM olugbẹsan tabi oluranro, ni Ashipa ti sọ pe "Gomina Seyi Makinde ti gba iṣẹ lọwọ ọkan lara awọn agbabọọlu to jẹ akọni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dá ọ̀gá ilé Keu tí wọ́n ti lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí i bàrà dúró
- Buhari, ohun ìjà tó ń kójọ ni wọn yóò lò láti rẹ́yìn Nàíjíríà - Fr Mbaka
- A kò da iṣẹ́ sílẹ̀ mọ́, ó di ọjọ́ míì, ọjọ́ re - IPMAN, PTD
- "Èmi ni mo sọ fáwọn ọ̀gá ilé Keu pé kí wọ́n lu ọmọ mi bí ẹran"
- Agbẹjọ́rò wọ́ ìjọba lọ sílé ẹjọ́ pé kó yọ kéú kúrò lára owó Náírà
- Buhari, ìwé òfin 1999 ni ìparun Naijiria, tètè fà á ya - Tunde Bakare
- Gómìnà Yoruba, ẹ dúró lé ìjọba àpapọ̀ lọ́rùn pé kó fi Sunday Igboho sílẹ̀ - Gani Adams
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dá ọ̀gá ilé Keu tí wọ́n ti lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí i bàrà dúró
- Ìdí rèé tí mo fi gbà kí ọkọ mi má a ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyá àti àbúrò mi
O ni agbabọọlu yii, Abubakar Adeyemi, to jẹ atamatase to n wọ jersey nọmba kẹrin, wa lara awọn akọni to gbe ikọ 3SC de ipele Premier Division.
Agbabọọlu naa si lo jẹ ọmọ oloye ẹgbẹ oṣelu PDP kan nipinlẹ Oyo, Adebisi Olopoeyan.
Ṣugbọn ko pẹ ti Ashipa gbe iroyin yii jade, ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu 3SC sọ pe irọ ni iroyin naa.
Wọn ni ko si agbabọọlu awọn kankan ti wọn da duro lẹnu iṣẹ.
Koda, wọn fikun pe agbabọọlu ti Ashipa darukọ rẹ naa gba owo oṣu Kẹsan-an pẹlu awọn akẹẹgbẹ rẹ, lọjọ ti iroyin naa jade.
Eyi si lo mu ki gomina pe ẹjọ tako Ashipa fun ibanilorukọjẹ, to si n beere biliọnu marun-un Naira gẹgẹ bi owo gba ma binu.
Ori ayelujara ni mo ti gbọ pe gomina Makinde pe mi lẹjọ - Ismaila Ashipa
Ẹni ti wọn pe lẹjọ naa, Ọgbẹni Ashipa sọ fun BBC pe oun ko ri iwe ipẹjọ naa gba.
O ni ori ayelujara l'oun naa ti kà pe gomina pe oun l'ẹjọ, to si sọ pe oun ko le sọ nkankan lori ọrọ naa lasiko yii.
PDP ni oun fara mọ igbsẹ gomina lati pe Ashipa lẹjọ:
Bakan naa ni agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Akeem Olatunji sọ pe ẹgbẹ naa faramọ igbesẹ ti gomina gbe.
O ni "o ti pẹ ti Ashipa ti ma n kọ iru awọn nkan bẹẹ, a si ti kilọ fun lọpọ igba.
"Nkan ti kii ṣe otitọ lo kọ nipa gomina".
O ni nitori pe Gomina Makinde jẹ ẹni to n gba ẹgbin mọra, ni ọpọ ṣe n fi iwọsi lọ ọ.
Ati pe ti Ashipa ba gba pe oun jẹbi, to si tọrọ idariji lẹyin ti ile ẹjọ ba dajọ tan, ni ẹgbẹ PDP to o le dasi ọrọ naa.
Amọ ni bayii, wọn ti pa oju opo ti wọn kọ iroyin 'eke' naa si rẹ .