Sex swingers: Kò sóhun tó burú níbẹ̀ kí èmi àti ìyá mi jọ maa pín ọkọ mi lóríi bẹ́ẹ̀dì - Madi Brooks

Yoruba lo sọ pe karin-kapọ, yiyẹ lo n yẹ ni.

Amọ ṣe bi ki iya ati ọmọ ma a ni ibalopọ pẹlu ọkunrin kan naa ni?

Ara mi o riri, iṣẹlẹ to yanilẹnu silẹ dẹrẹ-dẹrẹ ni eyi ti arabinrin kan fi fidio rẹ sita lori ayelujara Tik Tok, nibi to ti ṣọ pe ọna kan ṣosọ ti oun n gba mu inu ọkọ oun dun ni pe, o ma n ba iya ati aburo oun ni ibalopọ.

Obinrin naa, Madi Brooks, to jẹ ọmọ orilẹ-ede America sọ pe inu iya oun ati ọkọ oun dun si eto naa.

O ni idi ti oun fi n pin ọkọ oun jẹ pẹlu iya ati aburo oun ni pe lọjọ ti ibalopọ ko ba wu oun lati ṣe, iya oun lo ma n dele de oun.

"Mo ma n gba ki ọkọ mi ba iya mi sùn ni ọpọ igba laarin ọsẹ".

Bakan naa ni Mandi sọ pe kii ṣe iya oun nikan ni awọn jọ n kopa ninu eto naa, o ni aburo oun obinrin naa ma n 'ba ololufẹ oun ṣere'.

Fidio naa fa oriṣiriṣi ariwisi lori ayelujara Tik Tok, ti ọpọ si n ya ẹnu pe iru ki leyi.

Iru igbeyawo bayii kii sẹ tuntun, 'open relationship' ni wsn n pe e ni ede Gẹẹsi.

Ninu iru igbeyawo bẹẹ, tọkọ-taya ni anfaani lati ni ibalopọ pẹlu ẹlomiran lai jẹ pe wọn binu si ara wọn.