Oluwo: N kò lo "Private jet" torí mo kọ̀ láti máa ta ilẹ̀ aráàlú ní ìtàkutà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti ṣalaye idi ti ko ṣe tii maa rinrinajo kaakiri ninu ọkọ ofururu aladani.

Gẹgẹ bii ohun sọ, eredi rẹ ko ju pe oun kọ lati maa ta ilẹ awọn eeyan oun ni itakuta, ati pe oun ni itẹlọrun.

Oluwo lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Facebook rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adewale Akanbi ni oun ko le maa jaye ọlọbaa kaakiri nigba ti awọn eeyan ti oun jọba le lori yoo maa jiya.

O ni "Gẹgẹ bii Ọba, to ba jẹ pe mo yan lati jaye ni, o yẹ kii n ti maa lo ọkọ ofurufu aladani iyẹn ti mo ba n ta ilẹ awọn eeyan ti mo jọba le lori."

"Ṣugbọn mo mọọmọ yan lati sin wọn bayii ni ki awọn le sin mi lọjọ ọla."

"Ohun to ṣe pataki si mi ni lọwọ yii awọn eeyan mi, ọna Ọlọrun ni mo si fi n han wọn, kii ṣe ọna oriṣa kankan."

"Bi mo ṣe n gbe igbe aye mi ree, idi naa si ni wọn ṣe n bu ọla fun mi."

Oluwo jẹ ọkan lara awọn Ọba ilẹ Yoruba to maa n sọ ni gbangba pe Ọlọrun nikan ṣoṣo ni Ọba nitori ko si Ọba kankan lẹyin Ọlọrun.

Bakan naa lo tun maa n sọ pe ko tọ ki eeyan maa sin oriṣa miran yatọ si Ọlọrun Ẹlẹdaa.