You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oluwo: Èmí àti Alaafin ti gbà pé Nàíjíríà kò le pín, yóò wà lọ́kan ni
Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi, Telu Kinni, tun ti sọrọ lẹẹkan si tako idasilẹ orilẹede Oduduwa, to ni awọn eeyan kan n polongo rẹ.
Ọba Akanbi, mẹnuba ọrọ yii lasiko to n ba BBC Yoruba lori ohun to gbe re aafin Oyo lati fikunlukun pẹlu Alaafin lọjọ Aje.
Ọba alaye naa ni kii se asiko to kan iran Yoruba lati fa oludije fun ipo aarẹ kalẹ, la maa wa lọgun pe a fẹ da orilẹede Oduduwa silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ìgbà mẹ́fà tí Buhari rìnrin àjò lọ sókè òkun fún ìtọ́jú ara rẹ̀
- Gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ ìdíje àti bí o ṣe lè wo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrin Nàìjíríà àti ikọ̀ Lesotho
- Ẹ má fi òógùn babańlá wa lórí Nàíjíríà jóná torí ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Oduduwa - Oluwo
- Ó dára kí Orílẹ̀èdè Naijiria wa ní ìṣọ̀kan jú kí a pínyà lọ - Buhari
- Buhari, ààwẹ̀ gbígbà ṣú ọmọ Nàíjíríà, jọ̀ọ́ ṣètò ìdẹ̀rùn - Tinubu lọgun
- Buhari ń lọ ṣàyẹ̀wò ara ní London lásìkò táwọn dókítà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní ààdọ́ta ọ̀dọ́ kú lẹ́yìn àpèjẹ tí ọmọ Yahoo kan ṣe l'Akute?
- Ọkọ̀ típà pa ọlọ́kadà àti akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin ní Ibadan
Oluwo ni lootọ oun ko ni oludije kankan lọkan amọ gbogbo ọmọ Yoruba to ba jade pe oun yoo du ipo aarẹ lọdun 2023, ni oun yoo gbaruku ti lati de ipo naa.
O fikun pe ki ẹya Yoruba gba ipo aarẹ nikan lo le tan iya to n jẹ wa, agbara si wa ninu ki Yoruba fi ohun sọkan lati gbe eeyan wọn sipo aarẹ.
"Kii se igba ti Yoruba fẹ jẹ aarẹ yii lẹ mọ pariwo orilẹede Oduduwa, ẹ jẹ ka de ibẹ naa, ka si gbaruku ti ọmọ wa to ba dije nitori awa ni ipo naa tọ si, gbogbo nnkan si lo yẹ ka fi wa.
Ẹ jẹ ka ni suuru lasiko yii na, amọ ti ọmọ Yoruba ba de ipo, ti ko ba se daadaa, nigba naa la le sọ pe a fẹ maa lọ. Ẹ ma jẹ ki egun kankan tun sẹ lori wa."
Alaafin gba pẹlu mi pe o yẹ ki Naijiria wa ni isọkan lai yapa
Nigba to n salaye bi ijiroro rẹ ati Alaafin tilu Oyo se lọ, Oluwo ni oun ati Alaafin ti dijọ panupọ kede pe kawọn eeyan to n polongo fun agbekalẹ orilẹede Oduduwa lọ se mẹdọ na.
"Baba Alaafin ri ọgbọn ninu ohun ti mo sọ, ti wọn si gba pe lootọ lo yẹ ki Naijiria jẹ ọkan, ka si gburuku ti ọna ta fi ni aarẹ ti yoo wa lati ilẹ Yoruba.
Alaafin tun sọ fawọn eeyan to n polongo iyapa orilẹede Naijiria lati ni suuru, ki wọn dakẹ, ki wọn ma si polongo orilẹede Oduduwa mọ."
Oluwo ni lootọ ni iya n jẹ iran Yoruba, baa se kawe to, to si dun wa pupọ, a mọ a gbọdọ rọra nitori ta ba n sunkun, o yẹ ka maa riran.
Irẹpọ gbọdọ jọba laarin awọn ọba alaye, ki iran Yoruba si dari jin ara wọn
Oluwo, ninu ọrọ rẹ tun ni oun rọ Alaafin pe ko ri daju pe irẹpọ, isọkan ati igbọraẹniye jọba laarin gbogbo oriade to wa nilẹ Yoruba.
O ni gbogbo ikunsinu ati aawọ to ti waye sẹyin laarin awọn ọba ilẹ Yoruba ni ki Alaafin pari, ki igba ọtun pẹlu irẹpọ si de saarin wọn.
'Mo tun bẹbẹ pe kawọn ọmọ Yoruba to ba n bara wọn ja gbagbe ija ana, ki wọn mase binu mọ, ki wọn fi ọrọ idasilẹ orilẹede Oduduwa silẹ, ka si wa ni isọkan."
Se atunto lo yẹ ki ẹya Yoruba faramọ ni abi ko yapa?
Nigba ti Oluwo n fesi lori ibeere yii, Oluwo ni ohun toun n fẹ ni ka duro ni ọkan amọ ilana pinpin ipo agbara lati oke de isalẹ, ti wọn n pe ni Divolution of power in oun fara mọ.
"Ilana ki awọn gomina wa lagbara ju aarẹ lọ, ti ijọba apapọ ko si ni lagbara ju awọn ijọba ipinlẹ lọ, kawọn ipinlẹ kọọkan naa si ni ileesẹ ọlọpa tiẹ, ni mo fara mọ."
Eyi yatọ patapata si ilana atunto Nigeria ti wọn pe ni Restructuring, amọ ilana pinpin ipo agbara yoo mu adinku ba agbara ijọba apapọ, tawọn ijọba ipinlẹ yoo si lagbara si."
Ẹran dida kaakiri igboro jẹ asa atijọ, ki ijọba fofin de lo tọ
Oluwo tilu Iwo wa koro oju si iwa dida ẹran kaakiri eyi to ni o n faa wahala laarin ẹya gbogbo nilẹ yii.
Oriade naa ni asa atijọ gbaa, ti ko jẹ itẹwọgba mọ yika agbaye ni asa dida ẹran jẹko kiri, o si yẹ kijọba tete fi ofin de.
"Bi ijọba ba fofin de ẹran dida, awọn agbẹ ati darandaran yoo dinku, ki wọn si tun se idanilẹkọ fawọn darandaran nipa ilana ọsin ẹran laye ode oni.
Gbogbo ẹya lo ni ajinigbe ati apaniyan, kii se iran kan
Bakan naa ni Oluwo tun fikun pe gbogbo ẹya ni awọn eeyan to n jinigbe tabi gbe ni pa wa, eyi ko si jẹ idamọ ẹya kan.
"Gbogbo ẹya lo ni ọdaran, ko si yẹ ka maa lọgun pe ẹya kan lo n daran babi jinigbe.
Bí ọlọ́pàá ṣe ń tú afurasí Fulani ajínigbé sílẹ̀ ń bà mí nínú jẹ́ - Alaafin
Alaafin tilu Oyọ, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kkta ti yari mọ ileesẹ ọlọpa ilẹ wa lọwọ lori ọwọ to fi n mu awọn ẹsun tawọn eeyan ba fi kan afurasi ọdaran Fulani.
Alaafin fi apa janu lori ọrọ yii lasiko to n gbalejo Oluwo tilu Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi ni Aafin rẹ lọjọ Aje.
Ọba alaye naa ni ọpọ awọn afurasi Fulani ti ọwọ ba pe wọn n huwa ijinigbe, ti wsn si fa le ọlọpa lọwọ, ni wọn n pada tu silẹ ni ọna to mu aroye lọwọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ìgbà mẹ́fà tí Buhari rìnrin àjò lọ sókè òkun fún ìtọ́jú ara rẹ̀
- Gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ ìdíje àti bí o ṣe lè wo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrin Nàìjíríà àti ikọ̀ Lesotho
- Ó dára kí Orílẹ̀èdè Naijiria wa ní ìṣọ̀kan jú kí a pínyà lọ - Buhari
- Buhari, ààwẹ̀ gbígbà ṣú ọmọ Nàíjíríà, jọ̀ọ́ ṣètò ìdẹ̀rùn - Tinubu lọgun
- Buhari ń lọ ṣàyẹ̀wò ara ní London lásìkò táwọn dókítà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní ààdọ́ta ọ̀dọ́ kú lẹ́yìn àpèjẹ tí ọmọ Yahoo kan ṣe l'Akute?
- Ọkọ̀ típà pa ọlọ́kadà àti akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin ní Ibadan
- Kí ló dé tí Osinbajo, Aregbesola, Gbajabiamila atawọn mii kò fi péjú sí ọjọ́ ìbí Tinubu?
- A ti kẹ́kọ̀ọ́, a ti kọ́gbọ́n, lá ṣe ń fa ojú ọ̀dọ́ mọ́ra láti dìbò ní 2023 - PDP pariwo síta
Alaafin ni ilana idajọ Naijiria mẹhẹ pupọ, koda ilana naa ko sisẹ mọ rara, bẹẹ si ni ilana isejọba wa ti kuna, paapaa lori ọrọ eto aabo .
"Mo ti bawọn peju si oniruuru ipejọpọ ti wọn ti n jiroro nipa eto aabo, ti mo si dide pe awọn gomina ipinlẹ nija nitori aja ti ko le bunijẹ ni wọn lẹka eto aabo.
Bi ọga agba ọlọpa ba pasẹ pe ki wọn tu afurasi kan silẹ, ko si gomina ipinlẹ kankan to lasẹ lati ni ko ri bẹẹ.
A ti saayna to pọ lati mu awọn afurasi Fulani ajinigbe, ta si fa wọn le ọlọpaa lọwọ sugbọn ọpọ wọn ni wọn tu silẹ lẹyin o rẹyin, eyi to n mu ki ibanujẹ dori agba wa kodo."
Ẹ má fi òógùn babańlá wa lórí Nàíjíríà jóná torí ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Oduduwa - Oluwo
Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti ṣapejuwe ipolongo fun idasilẹ orilẹ-ede Yoruba, gẹgẹ bi nkan to yẹ ki ijọba ati awọn ọba alaye, o mojuto ni kiakia.
Lasiko to ṣe abẹwo si Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, ni aafin rẹ, ni Oluwo sọ ọrọ yii.
O ni ko yẹ ka fi laalaa awọn baba nla wa to ja fitafita lati sọ Naijiria di ọkan ṣoṣo, jona nitori awọn nkan to ṣe e yanju lai si wahala.
Ninu ọrọ tiẹ naa, Ọba Adeyẹmi koro oju si bi awọn daran-daran Fulani kan ṣe n pa awọn ọmọ Yoruba lori ilẹ wọn.
O ni o ṣe pataki fun ijọba apapọ lati tete mu ileeṣẹ ọlọpaa kuro ni abẹ idari ijọba apapọ gẹgẹ bo ṣe wa ninu ilana iṣakoso ti Naijiria n lo.
Bẹẹ lo si gboriyin fun Oluwo, fun akitiyan rẹ lati mu ki iṣọkan Naijiria duro.
Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Oluwo ti Iwo, Ọba Akanbi rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ Yoruba, lati lo ọgbọn ninu ipolongo wọn fun pinpin orilẹ-ede Naijiria.
O ni nkan to yẹ ki wọn o ṣe ni pe ki wọn o ṣe atilẹyin fun ọmọ Yoruba lati di aarẹ Naijiria, kii ṣe ki wọn o ma a lu ilu ituka.
Bakan naa lo bu ẹnu ẹtẹ lu bi awọn kan lara awọn ajijagbara naa ṣe n sọ ọrọ ti ko dara nipa awọn ọba nilẹ Yoruba.
Bakan naa lo rọ Alaafin, lati dari igbesẹ ti yoo mu iṣọkan ba igbimọ awọn lọbalọba nilẹ Yoruba.