Nigeria vs Lesotho prediction: Báwo ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Super Eagles àti Crocodiles yóò ṣe lọ?

Aago márùn ìrọ̀lẹ́ ni ìfẹsẹ̀wọnseẹ̀ láàrín ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà àti Lesotho yóò jọ figagbága lónìí ọja Iṣẹ̀gún ọgbọ̀n, oṣù kẹta ọdún 2021.

Ìrètí ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Super Eagles ni láti parí ifẹsẹwọnsẹ wọ́n fún pégedé Idije Afcon èyí sì ni láti borí Ikọ̀ Crocoldile Lesotho.

Pápá ìṣeré Teslim Balogun ní ìlú Eko ni ìdíje Ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrín ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Nigeria àti Lesotho náà yóò tí wáyé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé, dígbí ní ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà wá ni ìpele L tí wọ́n wà, ó túmọ̀ sí pé ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni ìdíje tó ni tí kò sì tó ń kan ti a n yọ àdá sí

Ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó tí gba ife ẹ̀yẹ náà nígbà mẹ́ta ló ti fi hàn lọ́sẹ̀ tó kọjá pé òun yóò kópa nínú Afcon yìí nígbà tó jáwé olúborí ni ìlú Benin Republic sùgbọ́n ó kù kí ó fakọyọ lórí Lesotho.

Àwọn Crocodiles Lesotho yìí ko tíì jáwé olúborí fún ìdíje kankan láti inú oṣù kẹjọ ọdún 2019 ti wọ́n sì fìdí rẹmi nínú ìodíje máràrún tí wọ́n ti kópa

Kí Lesotho tó le ni ààyè rárá láti pegedé nínú ìdíje ti yóò wáyé ní oṣù kíní ọdún 2022 ni Cameroon, ó yẹ kí wọ́n dojú Sierra Leone bolẹ̀ ni ọjọ satide ni, sùgbọ́n ó ṣe ni láànú pé, ọ̀mì ni wọ́n gbá tó sí jẹ́ ìgbà kẹta nínú ipele ti wọ́n wà.

Ìròyìn sọ pé orílè-èdè náà ni pọ́ntì mẹ́ta , èyí sì ytúmọ̀ sí pé, ànfàní kan soso ti wan ni ni èyí tí wọ́n fẹ́ gbà ni ìpele L tí wan bá jáwé olúborí lónìí.

Àwọn ọmọ ikọ̀ Gernot Rohr tí jáwé olúborí nínú ìdíje mẹ́ta tí wọ́n sì gbá ọ̀mì méjì nínú ìdíje márùn-ùn wọn, èyí sì tí fún wọ́n ni pọ́ntì mọ́kànlá tó sí ti fún wọ́n láànfàni láti wa ni ipò kejì.

Ikọ̀ Thabo Senong fìdírẹmi pẹ̀lú mẹ́rìn sí òdo lásìkò ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ rl pllú Nàìjíríà nínú oṣù kọkànlá lọ́dún 2019 kí wọ́n tó lu Benin ni ami ayò kan sí òdo nínú idíje tó tẹ̀lé lẹ́yìn ọdún kan, sùgbọ́n ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù náà ti gbá ọ̀mì odo sí odo pẹ̀lú Benin àti Sierra Leone nínú ìfẹ̀sẹwọnsẹ̀ méjì tí wan ti gbá báyìí.

Báwo ní ò ó ṣe wo Nigeria vs Lesotho?

Bí ìdíje náà bá ṣe ń lọ lọ́wọ́ ni ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán ìjọba àpaps yóò ṣe máa gbé (NTA)

[Nigeria vs Lesotho] Ìgbòkègbodò ọkọ̀ ní agbègbè Teslim Balogun Stadium

Ẹ̀wẹ̀, àjọ tó n mójú tó ìgbokegbodo ọkọ̀ nípìnlẹ̀ Eko (LASTMA) tí fi ìkéde síta lójú òpó twitter rẹ̀ pé, nítorí ìdíje Afcon láàrín Nigeria àti Lesotho yìí ìdíwọ́ díẹ̀ yóò wà fún ìgbòkègbodò ọkọ̀ ni gbogbo agbègbè pápá iṣére Teslim Balogun ni Surulere.

Nítorí náà, ó ni kí àwọn ènìyàn jìnà sí agbègbè náà láti aago mẹ́wàá owúrọ̀ sí ààgio mẹ́wàá alẹ́.

Àjọ náà gba àwọn awakọ níyànjú pé, gbogb ọkọ̀ tọ bá n bs wá sí agbègbè Teslim Balogun lati Ojuelegba àti Alaka/Eric Moore ko ni ọ̀nà míràn jú láti gba orí afára lọ.