You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
eNaira: CBN ṣe ìfilọ́lẹ̀ eNaira, owó àìrí àmọ́ tó le fi ra nkan bí Naira oníbébà
Banki apapọ Naijiria, CBN ti ṣe ifilọlẹ oju opo ayelujara itakun agbaye fun owo ori ayelujara eNaira.
Ọjọ Aje ni banki naa ṣe ifilọlẹ itakun agbaye naa, ṣaaju ọjọ kinni, oṣu Kẹwa ti wọn o ṣe ifilọlẹ owo tuntun naa ni gbangba.
Banki naa sọ pe owo yii yoo ṣe e ná lati ra nkan, gẹgẹ bi Naira ti a n na.
Banki CBN sọ pe eNaira yoo mu idagbasoke ba kara-kata ni abẹle ati nilẹ okeere, nitori pe eto sisan ati gbigba owo yoo dinwo, ti yoo si tun yára.
- 'Kàǹkàn ìbílẹ̀, òògùn, àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti fóònù lá bá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú obìnrin tí wọ́n dédé jù sí àdúgbò wa l'Akure'
- Ọbẹ̀ sọ̀ọ̀! Mọ síi nípa ìwé ìrìnà Visa f'áwọn awakọ̀ tírélà àti òṣìṣẹ́ ilé adìyẹ tí UK ń gbèrò
- Buhari san $500 fáwọn aláwọ̀ dúdú l‘Amẹ́ríkà láti takò ẹ̀hónú wa - Yoruba/Biafra Nation
- Iṣẹ́ abẹ tí Bola Tinubu ṣe ló fa àbẹ̀wò ọ̀pọ̀ èèyàn sọ́dọ̀ rẹ̀ - Fayemi
- Yàjó yàjó: Àwọn ajínígbé soro l'Eko, wọ́n jí Ọ̀gágun ojú òfurufú Sikiru Smith gbé
- Mo sún ìgbẹ́jọ́ yìí láàrin Princess àti Baba Ijesha síwájú di 21/10/2021 torípé ...- Adájọ́
Igbesẹ naa waye lẹyin ti banki naa fi ofin de awọn owo ori ayelujara 'Cryptocurrency'.
Iru owo wo ni eNaira?
Owo tuntun eNaira jẹ owó orí ayelujara lati ọdọ banki agba naa. Owo yii yoo jẹ nina gẹgẹ bi Naira onibeba.
Ki lo nii ṣe pẹlu apo asunwọn owo rẹ ni banki?
CBN sọ pe ikawọ oun ni eNaira yoo wa, ti awọn banki kekeeke yoo si ma a mojuto awọn owo ti o ba fi pamọ sọdọ wọn.
Wọn ni ipo kan naa ni eNaira yoo wa pẹlu Naira ti o le ri ni ojukoroju, ti o si le mu dani.
Wọn ni kii ṣe pe yoo rọpo owo ti a n na.
Amọ dipo lilọ si banki lati ṣi apo asunwọn, ori ayelujara App eNaira ti wọn pe orukọ rẹ ni "Speed", ni wa a ti si apo asunwọn.
O si le lo App yii lori foonu rẹ bi ti awọn banki to n lo tẹlẹ.
Bakan naa, o le so asunwọn eNaira rẹ mọ apo asunwọn rẹ ni banki.