Classroom collapse on pupils in Ogun: Muinat Ilebiyi gbẹ́mìí mì lójú ẹsẹ̀, ipò táwọn méjì tó kù wà rèé

Ọmọ ile ẹkọ Nazareth High School kan ni agbegbe Imeko, ipinlẹ Ogun ti gbẹmi mi labẹ kilaasi to wo lu oun atawọn akẹgbẹ rẹ meji mii.

BBC Yoruba kan si Komisọna fun eto iroyin ni ipinlẹ Ogun, Họnọrebu Waheed Odusile to si sọ pe lootọ lo ṣẹlẹ.

Waheed ni ikọ ẹka eto ẹkọ ijọba ipinlẹ Ogun ti gbera lọ si ile iwe naa tori naa awọn ko tii le sọ pato igbesẹ ti ijọba yoo gbe lori rẹ afi ti wọn ba pada de.

Ẹwẹ, o fi idaniloju han pe ijọba yoo wa nkan ṣe dandan.

Iroyin sọ pe ṣaadede ni kilaasi naa wo lu awọn ọmọ to n kọ ẹkọ naa to si pa Muinat Ilebiyi loju ẹsẹ ti awọn meji to ku si farapa.

A gbọ pe wọn ti gbe awọn to farapa lọ si ile iwosan fun itọju ti wọn si ti sin oku Muinat naa ni ilana ẹsin Islam.

"Iṣẹlẹ naa jẹ eyi to ba ni lọkan jẹ pupọ to si jẹ ibanujẹ ọkan. Mo lọ si ile iwosan ti ọmọdebinrin to farapa yananayana ti n gba iwosan, o ti n yara diẹ diẹ".

Kansilọ Wọọdu Imeko, Họnọrebu Samuel Sunday Ojoawo sọ fun awọn oniroyin pe awọn adari to wa ni ijọba ibilẹ Imeko ti paṣẹ bayii pe ki wọn wo gbogbo ile ẹkọ naa palẹ patapata.