You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kebbi boat accident: Wọn ti yọ òkú ọgọ́ta èèyàn nínú àwọn tó ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ
Wọn ti ri oku eeyan ọgọta yọ ninu omi lara awọn to ba iṣẹlẹ ọkọ oju omi ni ipinlẹ Kebbi lọ.
Eayan to le lọgọrun un lo wa ninu ọkọ oju omi naa nigba ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
Awọn eeyan ọhun n rinrinajo lọ si ipinlẹ Niger lati Kebbi ki ọkọ ti wọn wa ninu rẹ to pin si meji laarin agbami.
- Wo ohun màrùn-ún pàtàkì nípa ọ̀gá ológun tuntun
- Èpè elépè kò ní ràn ẹ́, aya Ajeyemi! Wo àwọn òṣèré tó ń fi àdúrà ré èpè ESABOD kúrò lóríi Toyin Abraham
- Ìgboro ayélujára ń gbóná lọ́wọ́lọ́wọ́ mọ́ Remi Tinubu lẹ́yìn tó pe obìnrin kan ní Tọ́ọ̀gì
- Èèyàn bíi 156 di àwátì bí ọkọ̀ ojú omi ṣe dédé là sí méjì láàrin agbami
- A fọwọ́ sí ìṣọ̀kan Nàíjíríà gẹ́gẹ́ bi ọmọ ẹgbẹ́ APC - Akeredolu, Fayemi
- Ẹ̀yin aṣaájú APC, ẹ́ kábáàmọ̀ ìpinnu tẹ ṣe lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation - Akitoye
- Ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation ń fa aáwọ̀ láàrin Gani Adams àti Sunday Igboho
- Kàyéèfì! Ọwọ́ tẹ òkú tó ń ká àwọn èèyàn mọ́lé, to sì ń jà wọ́n lólè dúkìá
Eeyan mejilelogun ni ijọba Kebbi kọkọ ri doola gbara ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ tan.
Ọpọ igba ni ijamba ọkọ oju omi ma n waye lori odo Niger, paapaa ti omi naa ba ti kun si i nitori ojo.
Bí èèyàn bíi 156 di àwátì bí ọkọ̀ ojú omi ṣe dédé là sí méjì láàrin agbami
Ogunlọgọ eeyan ti di awati lẹyin ti ọkọ oju omi ti wọn wa ninu rẹ rì sinu omi nipinlẹ Kebbi.
Obinrin ati ọmọde lo pọ ju ninu awọn eero ọkọ naa to n rinrinajo lati ipinlẹ Niger ni owurọ Ọjọru, ki ọkọ wọn to ri.
Awọn alaṣẹ ni Kebbi sọ fun BBC pe awọn oṣiṣẹ adoola ati awọn to le wẹ ninu odo n ṣiṣẹ lọwọ lati doola iye ti wọn ba le ri ninu awọn eeyan naa.
"Ogun eeyan lati doola ni aaye, awọn mẹrin ti ku, ti a si n wa eeyan 96 to kù ti a gbagbọ è diẹ lara wọn ṣi wa ni isalẹ odo."
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe eeyan to le ni 160 lo wa ninu ọkọ oju omi naa nigba to deede là si meji laarin agbami.
Ọpọ igba ni ijamba ọkọ oju omi ma n waye lori odo Niger, paapaa ti omi naa ba ti kun si i nitori ojo.
Ijamba kan waye lori odo naa ni ibẹrẹ oṣu Karun-un.
Akunfaya si jẹ ọkan lara awọn nkan to ma n fa ijamba ọkọ oju omi.
Aarẹ Buhari naa si ti kẹdun lori ijamba naa, to ṣapejuwe pe adanu nla ni.