Ijede Lagos Boat Mishap: Mi ò rí irí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí rí láyé mi!

Ẹbi awọn to ba iṣẹlẹ ọkọ oju omi to da nu ni agbegbe Ijede ni ilu Eko sọ ipo ti gbogbo agbegbe omi ti wọ n gba kọja yii wa.

Alhaja Fatimah Aṣabi sọ fun ik iroyin BBC pe eeyan oun mẹta lo wa ninu iṣẹlẹ naa ti wọn ko si tii ri meji ninu wọn. Bẹ́ẹ si ni ninu ile to n gbe gan eniyan mẹrẹ lo wa ninu iṣẹlẹ naa.

O bu ẹnu atẹ lu ipo ti ibudokọ oju omi Ijede si Ikorodu wa o si lo anfani yii lati parọwa si ijọba Naijiria.

Ileeṣẹ LASEMA ṣàlàyé pè ìjàmbá náà wáyé lálẹ́ ọjọ́ Abamẹta nígbà tí ọkọ̀ ojú omi ọ̀hún kọsẹ̀.

Ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, ti parọwa sara ilu lati sọra fun wiwọ ọkọ oju omi lalẹ.

Ikilọ yi waye lẹyin iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi to danu ni Egbin, lagbegbe Ikorodu lalẹ ọjọ Abamẹta.

LASEMA sọ pe eeyan mẹrinla ninu awọn mọkanlelogun to wa ninu ọkọ oju omi naa ni wọn ṣi n wa.

Eeyan mẹrin ni wọn ribi dooola amọ oku mẹta ni o ti foju han pe o ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ninu atẹjade kan ti Adebayo Kehinde, agbẹnusọ LASEMA fi sita salaye pe igbiyanju lati doola ẹmi ṣi n tẹsiwaju nipaṣẹ ajọsepọ awọn pẹjapẹja lagbegbe naa ati awọn ọlọpaa oju omi.

Kehinde to n sọrọ lorukọ ọga agba LASEMA, Oluwafẹmi Oke-Osanyintolu sọrọ lori pataki ki awọn ara ilu tẹle awọn ofin to de irinna oju omi.

Titi di bi a ti ṣe n kọ iroyin yi, a ko tii gburo pe wọn ti ri oku awọn elomiran lẹyin awọn ti LASEMA ti kede saaju.

LASEMA rọ awọn to ba n wa mọlẹbi wọn ti wọn fura si pe o le wa ninu ijamba naa lati kan si ile iṣẹ ọlọpaa eti odo.

Iwadii ṣi n lọ lọwọ gẹgẹ bi ohun ti LASEMA sọ.

Wọn ni àwọn ṣi n ṣe iwadii lori ohun to fa ijamba ọkọ naa.