You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wọn dóòlà ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èrò níbi ìṣẹlẹ̀ ilẹ̀ rírì erékúṣù Lombok
Irinajo afẹ́ to di irinajo to n gbẹ̀mí àwọn ènìyàn ni Indonesia.
Odiwọn iye awọn to ti ku nibi iṣẹlẹ ilẹ riri nla to ṣẹlẹ ni Lombok ti di mejidinlọgọrun bayii.
Awọn ti wọn farapa ti le ni igba.
Awọn agbegbe to bajẹ julọ ni bii abule Lading-Lading, ilu Mataram, ati àwọn agbegbe miran ni ariwa Lombok.
Bayii wọn ti ko ọpọlọpọ àwọn èrò lọ kuro ni Gili nibi ti wọn ṣi ti n ko àwọn arinrinajo kuro pẹlu ọkọ oju omi.
Ọpọ àwọn to wa ni erekuṣu naa ni ebi n pa wọn nitori ko si omi to ṣee mu ati ohun jijẹ ni eyi ti awọn eniyan ti n fẹ huwa ipá.