You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Patience Jonathan gbójú kúrò lára owó ẹ - Ilé ẹjọ́ gíga lEko
Ìyàwó ààrẹ orílẹ̀èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Dame Patience Jonathan ti pàdánù $8.4m àti N9.2b sọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ orilẹ̀ede Nàìjíríà.
Eyi waye lẹyin abajade idajọ adajọ agba, Mojisola Olatoregun ni ile ẹjọ giga to wa ni ipinlẹ Eko to si paṣẹ pe ki iyawo aarẹ Patience Jonathan lati gbagbe $8.4m àti N9.2b rẹ tori o ti bọ sọwọ ijọba.
Adajọ agba, Mojisola Olatoregun tẹ pẹlẹ mọ ọ pe wọn funra pe owo naa jade latari iwa magomago.
Nitori naa, o gba ẹjọ ti ajọ EFCC pe wi pe ki Patience padanu owo naa pata pata.
Awọn Iroyin ti ẹ le nifẹ si
Idajọ naa sọ ajọ EFCC di ajawe olubori gẹgẹ bi adajọ ṣe ni arabinrin Jonathan ko ni aridaju lati fi han pe ọna to tọ ni oun fi ri owo naa ati idi ti wọn ko fi ni gba owo naa lọwọ rẹ.
Ile ẹjọ ni gẹgẹ bi ajọ EFCC ṣe sọ ọ, ọns ti Patience gba ri owo naa lodi si abala ofin ikẹtadinlogun to ni ṣe pẹlu jiji owo atawọn ẹsun mii to fara pẹ ẹ.
Ajọ EFCC ti fi aridaju eyi han nipa fifi si oju opo Twitter wọn.