Coronavirus Cases in Africa:Ẹ wo bí ìpínlẹ̀ Eko, Ondo àti Oyo yóò ṣe dá ilé ìjọ̀sìn padà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Awọn alaṣẹ ni ipinlẹ Eko, Ondo ati Oyo ti fi lede ọna ti wọn yoo gba lati sin awọn ile ijọsin pada ni ipinlẹ wọn.

Eyi jadẹ ninu atẹjade ti awn Gomina ipinlẹ mẹtẹẹta naa fi si oju opo ikansiraẹni Twitter wọn.

Amọ Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti fi lede lati ọdọ ajọ amuṣẹya lorilẹede Niajiria pe iṣede yoo tẹsiwaju fun ọsẹ meji miran lorilẹede Naijiria lati kapa arun Coronavirus.

Nibayii iye awọn to ti ni arun naa lorilẹede Naijiria ti le ni ẹgbẹẹta bayii.

Ipinlẹ Eko

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lasiko to n ṣe ipade lori igbesẹ ti wọn n gbe lati koju arun Coronavirus sọ wi pe awọn ti ṣe ipade pẹlu awọn adari ile ijọsin ati awọn imaamu ni ipinlẹ Eko.

Abajade ipade naa si ni pe ile ijọsin ko i tii le ṣi lasiko yii, amọ awọn yoo tẹsiwaju lati ma a gba awn adari ile ijọsin ni imọran lori arun Coronavirus ati bi o ṣe lẹwu si ni ibi ti awọn eniyan ba parapọ si.

Awọn adari ile ijọsin ati imaamu naa si sọ wi pe awọn ni igbagbọ ninu aṣẹ ijọba ati wi pe wiwa ni alaafia awọn eniyan jọ wọn loju.

Ipinlẹ Oyo

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde kede wi pe ijinasiraẹni gbọdọ tẹsiwaju ni ipinlẹ naa nitori iye awọn to n ni arun naa n peleke si ni ipinlẹ naa.

Makinde ni nitori naa ni oun ṣe bẹrẹ si ni gbe e yẹwọ asiko ti ile ijọsin le pada bẹrẹ ijọsin nitori awọn ile ijọsin ti kọwe si oun, ti wọn si n bere aṣẹ lati ma a ṣe ẹsin pada ninu ijọ wọn.

Gomina naa ni oun yoo ṣe ipade pẹlu awọn adari ile ijọsin ni ipinlẹ naa ki ọsẹ yii to pari lati fi igbesẹ oun han si awọn eniyan.

Bẹẹ lo fikun pe iwadii fihan pe arun Coronavirus ni agbara lati tankalẹ ju bo ṣe lọ nibi ti awọn eniyan ba fun pọ si.

Nitori naa ni oun gbogbọ ṣe iwadii daradara lati mọ ewu to wa ninu ṣiṣi awọn ile ijọsin pada.

Ipinlẹ Ondo

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti fi da awọn asaaju ile ijọsin loju wi pe oun yoo ṣe ipade pẹlu wọn lati jiroro lori bi awọn ile ijọsin naa yoo ṣe bẹrẹ pada.

Akeredolu ni oun yoo si tete ṣe agbeyẹwo ọna abayọ ti ijiroro naa ba la kalẹ lati ri wi pe lilọ si ile ijọsin pada si awujọ wọn.

Bẹẹ ni Gomina naa dupẹ lọwọ awọn eniyan pẹlu bi wn ṣẹ tẹlẹ ofin ijọba lori ijinasiraẹni, nitori ilera ara wn ṣe pataki lati bori itankalẹ arun Coronavirus.

Kó má a lọ bẹ̀ ẹ́ ní ìséde coronavirus fún ọ̀sẹ̀ méjì míràn - Ìjọba Nàìjíríà

Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti kede pe isede yoo tẹsiwaju fun ọsẹ meji miran.

Alaga igbimọ amuṣẹya ti ijọba gbe kalẹ, Boss Mustapha lo kede aṣẹ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Abuja lọjọ Aje.

Mustapha sọ pe bi nkan ṣe wa ni asiko yii naa ni yoo ṣi wa titi di ọjọ kinni, oṣu Kẹfa, ọdun 2020.

Ṣugbọn fun ipinlẹ Kano, isede tọsan-toru ni yoo ṣi wa nibẹ.Ijọba apapọ ti sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko ni ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lọni lori ibi ti iṣẹ de duro lori ajakalẹ arun Covid-19.

Ṣaaju ni olubadamọran agba fun aarẹ lori ọrọ to n lọ, Femi Adesina kede loju opo Twitter rẹ pe Aarẹ Buhari ko ni ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lọjọ Aje.

Adesina sọ pe aarẹ ko pinnu lati ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ, ati pe ohun yowu to ba yẹ ki awọn eeyan mọ nipa ibi iṣẹ de duro lori arun Coronavirus ni igbimọ amuṣẹya ti aarẹ gbe kalẹ yoo fi to awọn eeyan leti.

Ṣaaju ni iroyin kan kan ti gbode pe aarẹ yoo ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lalẹ ọjọ Aje, papa julọ lori igbesẹ to kan lori igbele to n lọ lọwọ lawọn ipinlẹ kan nitori arun Coronavirus.

Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ń fẹ́ kí òfin kónílé-ó-gbélé kásẹ̀ nílẹ̀ ní Nàìjíríà

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ti fi ẹro wọn han lori ẹrọ ayelujara lori ohun ti wọn lero pe Aarẹ Buhari yoo sọ lori arun Coronavirus.

Awọn to n fi ẹrọ wọn lede lara awọn ololufẹ ile iṣẹ BBC lori ẹrọ ibanisọrọ Facebook sọ wi pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari fi opin si ofin konile-o-gbele lorilẹẹde naa.

Bakan naa ni wọn n bere fun ki aarẹ gbekile ofin to de irinna lati ipinlẹ kan si omiran lorilẹede Naijiria.

Lara wọn sọ wi pe iya ati iṣẹ lorilẹede Naijiria kọja bo ṣe yẹ lasiko ofin konile o gbele lorilẹede Naijiria.

Wọn kesi aarẹ Buhari lati bojuwo awọn mẹkunu nitori ibi n pa mọ.

Amọ, awọn miran n gba awọn eniyan ni imọran lati ni igbagbọ ninu Aarẹ Buhari wi pe yoo ṣe ohun to tọ fun awọn ọmọ Naijiria.

Bakan naa ni awọn miran sọ wi pe oun ti aarẹ Buhari yoo ṣe ni lati fi ọsẹ meji kun ọjọ ti ofin konile-o-gbele yoo dopin ni Naijiria.

Nibayii, Orilẹede Naijiria ti ni eniyan mejidinlogojilelẹlọọdurun(5,959) lo ti ni arun Coronavirus ni Naijiria.

Bẹẹ ni iye awọn to ti ri iwosan gba ti da mẹfadinlẹgbẹjọ, ti eniyan mejilelọgọsan si ti ri iwosan gba.

Ẹ̀ wo àwọn ìgbéṣẹ̀ tí ó ṣeeṣe kí ìjọba àpapọ̀ gbé lórí òfín kónílé ó gbélé ní Eko, Abuja, Ogun

AjọAmuṣẹya ti Aarẹ Buhari gbekalẹ lori arun Coronavirus,PTF yoo ṣe ipade lọni lati ṣe agbeyẹwo ofin konile-o gbele ni Naijiria.

Ajọ amuṣẹya naa yoo ma a woye igbesẹ ti wọn yoo gbe lori ofin konile-o-gbele to n lọ lọwọ ni ipinlẹ Eko, Ogun ati ilu Abuja.

Kini awọn igbesẹ to ṣeeṣe ki Ajọ Amuṣẹya lori arun Coronavirus,,PTF gbe loni?

  • O seese ki ofin konile-o-gbele tẹsiwaju fun ọsẹ meji ni ipinlẹ Eko, Ogun ati Abuja
  • Wọn le e gbegile ofin konile-o-gbele, eleyii ti yoo fayegba itankalẹ arun Coronavirus lati agbeegbe kan si omiran.
  • Bakan naa ni wọn si le e gbe igbesẹ lati ri wi pe awọn ijọba ipinlẹ kọọkan gbe igbesẹ fun ara wọn.
  • Bakan naa ni wọn yoo gbe igbesẹ lori lilo agbo tabi ọna ibilẹ lati fi koju arun Coronavirus.

Lorilẹede Naijiria bayii, iye awọn eniyan to ti ni arun Coronavirus naa ti da ẹgbẹrun marun ati mọkanlelogunlelẹgbẹta (5,621).

Eniyan mejilelaadọrinlenirinwo( 1742) lo ti ri iwosan gba, nigba ti eniyan mẹrindinlọgọsan to ti papoda nitori arun Coronavirus.

Ilúmọ̀ọ́ká oníròyín, Ayinde Soaga ti jàjàbọ́ lọ́wọ́ àrun Covid-19

Ilumọọka oniroyin orileede Naijiria, Ayinde Soaga ti moribọ lọwọ arun Covid-19.

Lẹyin ayẹwo , o sọ pe awọn to n tọju ohun ni ko sewu ki oun maa lọ sile laayọ ati alaafia.

Nigba ti akọroyin BBC kan si lori ago, o fidi ọrọ yii mulẹ to si ni alẹ ọjọ Eti ni wọn ni ki oun maa pada sile.

Bi a ko ba gbagbe ni nkan bi ọsẹ meji sẹyin ni iroyin gbode pe o ti ko arun Covid-19.

Ko pẹ si igba ti iroyin jade lo ni lootọ ni to si bẹrẹ si ni gba itọju ni ibudo iyasọtọ ni ipinlẹ Katsina.

Ẹ̀ wo àwọn ìgbéṣẹ̀ tí ó ṣeeṣe kí ìjọba àpapọ̀ gbé lórí òfín kónílé ó gbélé ní Eko, Abuja, Ogun

AjọAmuṣẹya ti Aarẹ Buhari gbekalẹ lori arun Coronavirus,PTF yoo ṣe ipade lọni lati ṣe agbeyẹwo ofin konile-o gbele ni Naijiria.

Ajọ amuṣẹya naa yoo ma a woye igbesẹ ti wọn yoo gbe lori ofin konile-o-gbele to n lọ lọwọ ni ipinlẹ Eko, Ogun ati ilu Abuja.

Amọ ni ipinlẹ Ogun, Gomina Dapo Abiodun ti fi ọsẹ kan kun ofin konile-o-gbele naa nitori awọn eniyan ko bọwọ fun ofin yiyagofunraẹni, eleyii to n mu ki iye eniyan to ni arun naa ni ipinlẹ ohun peleke si.

Ni ipinlẹ Eko, Gomina Babajide Sanwo Olu ti kede wi pe ti awọn eniyan ba kọ lati tẹlẹ asẹ konile-o-gbele, yiyagofunraẹni ati fifọwọ ni gbogbo igba, oun yoo paṣẹ ki konile-o-gbele ọlọjọyipo pada.

Kini awọn igbesẹ to ṣeeṣe ki Ajọ Amuṣẹya lori arun Coronavirus,,PTF gbe loni?

  • O seese ki ofin konile-o-gbele tẹsiwaju fun ọsẹ meji ni ipinlẹ Eko, Ogun ati Abuja
  • Wọn le e gbegile ofin konile-o-gbele, eleyii ti yoo fayegba itankalẹ arun Coronavirus lati agbeegbe kan si omiran.
  • Bakan naa ni wọn si le e gbe igbesẹ lati ri wi pe awọn ijọba ipinlẹ kọọkan gbe igbesẹ fun ara wọn.
  • Bakan naa ni wọn yoo gbe igbesẹ lori lilo agbo tabi ọna ibilẹ lati fi koju arun Coronavirus.

Lorilẹede Naijiria bayii, iye awọn eniyan to ti ni arun Coronavirus naa ti da ẹgbẹrun marun ati mọkanlelogunlelẹgbẹta (5,621).

Eniyan mejilelaadọrinlenirinwo( 1742) lo ti ri iwosan gba, nigba ti eniyan mẹrindinlọgọsan to ti papoda nitori arun Coronavirus.

Ilúmọ̀ọ́ká oníròyín, Ayinde Soaga ti jàjàbọ́ lọ́wọ́ àrun Covid-19

Ilumọọka oniroyin orileede Naijiria, Ayinde Soaga ti moribọ lọwọ arun Covid-19.

Lẹyin ayẹwo , o sọ pe awọn to n tọju ohun ni ko sewu ki oun maa lọ sile laayọ ati alaafia.

Nigba ti akọroyin BBC kan si lori ago, o fidi ọrọ yii mulẹ to si ni alẹ ọjọ Eti ni wọn ni ki oun maa pada sile.

Bi a ko ba gbagbe ni nkan bi ọsẹ meji sẹyin ni iroyin gbode pe o ti ko arun Covid-19.

Ko pẹ si igba ti iroyin jade lo ni lootọ ni to si bẹrẹ si ni gba itọju ni ibudo iyasọtọ ni ipinlẹ Katsina.

Emi kọ o,awọn ọmọ yahoo yahoo ti gbakoso oju opo mi

Amọ sa akọroyin naa ti fi ikilọ sita pe ki awọn ara ilu sọra fawọn alaburu ori ẹrọ ayelujara ti wọn ti gbakoso ikanni ibaraẹnisọrọ rẹ ni Facebook.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu akọroyin BBC Ayinde Soaga ni lati ọjọ Kẹsan osu Kẹrin ni awọn gbajuẹ ti gbakoso oju opo oun ti o si ni gbogbo ohun ti awọn eeyan ba ri nibẹ ko ti a ti ọwọ ohun wa.

''Mi o fi ọrọ idupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria kankan si oju opo naa bẹ si ni mi o kan si ẹnikẹni lati wa sowo sogundogoji kankan.

Mo rọ yin lati yago fun iru ọrọ bẹ''

Ìlúmọọká akọròyìn NTA Nàìjíríà, Ayinde Soaga lùgbàdì Covid 19

Egbẹ akọroyin orile-ede Naijiria ẹka ipinlẹ Katsina tibanujẹ lori bi ọkan lara wọn, gbajugbaja akọroyin ni, Ayinde Soaga, ti se lugbadi arun Coronavirus.

Soaga to tun jẹ ọga agba ile isẹ amounmaworan Naijiria, NTA Katsina ni ẹgbẹ naa sọ ninu atẹjade pe ayẹwo fihan pe o ni Covid-19.

Pupọ awọn akọroyin ni o wa ninu ewu arun yi ni Naijiria nipasẹ lilọ bibọ lati le se akojọpọ iroyin faraye gbọ.

Alaga ẹgbẹ naa, Tukur Dan Alli, sọ pe asiko yi lawọn akọroyin nilo iranwọ ijọba ati awọn aladani lati le daabo to peye bo wọn.

O kesi ijọba ati awọn ti o lẹnu lọrọ lẹka iroyin lati pese irinsẹ idaabobo ẹni ati awọn nkan miran to le ko awọn akọroyin yọ́ lọwọ arun Covid 19.

Ọmọ bibi Ẹgba Gbagura ni Ayinde Soaga jẹ nipinlẹ Ogun.

Eeyan meje lo ti dero ọrun nipasẹ Covid 19 nipinlẹ Katsina to jẹ ipinlẹ ti aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari ti wa.

Losu kẹta ọdun yi ni wọn kede ẹni akọkọ to safihan arun yi.

Lati igba naa disin,awọn mẹtalelọgbọn lo n gba itọju ni ileewosan lori arun yi ti iroyin si sọ pe mẹfa lara wọn ti ya lẹyin tayẹwo ni ko si arun naa lara wọn mọ.

Ọkọ̀ ojú omi dànù ní Kwara, ọmọ́dé 9 ba rìn

Ìjàmbá Kwara: Isẹ́ ìdárò ń wọlé sọ́dọ̀ ìjọba Kwara

Ilu Lafiagi, nijọba ibilẹ Edu nipinlẹ Kwara ni ọkọ oju omi to ko ero mejilelogun naa ti danu lagbami.

Kowee ke, ko ha nilu Lafiagi nipinlẹ Kwara lopin ọsẹ nigba ti ọkọ oju omi kan, to ko ero mejilelogun, ti ọpọ wọn jẹ ọmọde, danu ni agbami odo Niger, lasiko ti wọn bọ lati ibi ayẹyẹ igbeyawo kan.

A gbọ pe bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan tiraka lati doola ẹmi awọn ero omi naa, amọ aayan wọn ko fi bẹẹ ni ipa, tori ọmọde mọkandinlogun lo si papa ba isẹlẹ naa rin, ti wọn si gba ẹmi eeyan meji la.

Titi di irọlẹ ọjọ Satide si ni wọn n yọ oku awọn eeyan to ba isẹlẹ naa rin, tawọn ọlọpaa atawọn osisẹ panapana naa si n tiraka lati sisẹ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wayi o, Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed ti ba Emir tilu Lafiagi, Alhaji Saadu Kawu Haliru kẹdun,lori iku awọn eeyan to ba ijamba omi naa lọ.

Atẹjade kan ti akọwe eto iroyin gomina Ahmed, Abdulwahab Ọba fisita wa se apejuwe iku awọn eeyan naa bii adanu ati ofo nla fawọn ẹbi wọn, ati ipinlẹ Kwara lapapọ.

Bakan naa, aarẹ ile asofin agba, to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kwara, Dokita Bukọla Saraki, naa ti daro lori iku awọn eeyan naa.

Nigba to n kẹdun loju opo Twitter rẹ, Saraki ni lasiko yii tawọn eeyan ilu Lafiagi n se ọfọ awọn eeyan wọn yii, oun wa gbadura pe ki Ọlọrun fun wọn ni ẹmi lati gba adanu naa mọra, ki ara awọn eeyan tori ko tọ ninu ijamba naa si tete mokun pada.