countries without coronavirus: Ọwọ́jà coronavirus yóò ṣì wà pẹ̀lú àgbáyé fún ìgbà pípẹ́- Ngozi Okonjo-Iweala

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Minisita feto iṣuna lorilẹede Naijiria nigbakan ri, Ọmọwe Ngozi Okonjo Iweala ti ṣalaye pe ọwọja arun coronavirus yoo ṣi wa pẹlu gbogbo agbaye fun igba pipẹ ẹẹyin ti arun naa ba kasẹ n lẹ.

Ọmọwe Ngozi Okonjo Iwealla ni ko si aniani pe eto ọrọ aje agbaye gbogbo ni yoo dẹnukọlẹ eleyi to tums si pe kini naa yoo kan awọn orilẹede Afirika pẹlu.

Amọṣa o ni ọna kan pataki lati bori wahala to lee waye lori eto ọrọ aje lẹyin ajakalẹ arun naa ni ki olukuluku orilẹede ni ilẹ Afirika o boju wo inu ile rẹ lati lo awọn ohun ti o ba ni fi gbe ara rẹ dide.

Ọmọwe Okonjo-Iwealla to ba BBC News Sọrs ṣalaye pe ko si nnkan meji ti awọn orilẹede lorilẹ Afirika lee fi gba ara wọn la ju awọn ẹka bii eto ogbin atawọn ohun alumsni miran ti Eleduwa fi jinkin wọn ati pe ki banki apapọ na ọwọ iranwọ si awọn ileeṣẹ kerejekereje nitori pe ẹka wọnyii lo gba ọpọlọpọ awọn eeyan lawsn orilẹede wọnyii si iṣẹ julọ.

O wa fi kun un pe kọkọrọ kan to n bẹnu aja jẹ lori ọrọ yii ni pe awọn orilẹede Afirika ko ni owo lati fi awọn nnkan wọnyii lọwọ; idi niyi ti wọn si fi nilo ati tọ awọn ileeṣẹ nlanla lagbaye lọ lati yawo ni ele ti ko ga ju ara lọ.

Wo àwọn bẹbẹ tí Umar Musa Yar'adua ṣe lórí àlééfà

Ọjọ́ ńlá, ọjọ́ manigbagbe ni ọjọ́ karùn-ún oṣù karùn-ún ọdún 2010, tí aarẹ tẹ́lẹ̀ ni Nàìjíríà, Umaru Musa Yar'adua jáde láyé, èyí tó pé ọdún mẹ́wàá gbáko lónìí ọjọ́ Isegun.

Lásìkò tí Umar Yar'adua sì jẹ Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí, ọ̀pọ̀ igbesẹ tó pegede lo gbé fún idagbasoke ilẹ̀ Nàìjíríà àti igbaye-gbadun ọmọ orílẹ̀ èdè yìí kọ̀ọ̀kan.

Yoruba sì ni bí onirese kò bá fín igbá mọ, èyí tó ti fin silẹ kò leè parun, ìdí si nìyí tí BBC Yoruba fi ń mú àwọn iṣẹ́ akainiye tó jẹ́ manigbagbe fún àwọn ọmọ Nàìjíríà, tí Ààrẹ Yar'adua gbé orí àkóso ṣe nígbà ayé rẹ.

Ohun rere tí Umar Yar'adua ṣe lórí aleefa:

Ìkéde dúkìá faraye:

Ohun àkọ́kọ́ tí Ààrẹ tó ti di olóògbé náà ṣe lórí àga àkọ́so, tí a kò leè gbàgbé ni pé òun ni aarẹ àkọ́kọ́ tó kéde dúkìá rẹ fún gbogbo ayé, lai ju ọgbọn ọjọ́ lọ tó di Aare, èyí tó sì dun mọ àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú pupọ.

Ìkéde dúkìá tí Yar'adua ṣe yìí, si ni àwọn èèyàn fi ń ṣe odiwọn fún Ààrẹ tuntun to ń jẹ lẹ́yìn rẹ, láti mọ bóyá onítọ̀ún yóò kó akoyawọ bíi Umar Yar'adua.

Ayédèrú èsì ibo:

Ohun èkejì tí Yar'adua tún ṣe daada ni pé, ó

gbà pé èsì ìbò tó gbé òun wọlé kún fún magomago àti ayédèrú esi ibo.

Ìkéde yìí ló gbà gbogbo àgbáyé kan, tí wọn sì ń kan saara sì pe olóòótọ́ èèyàn ni.

Bákan náà lo tún fi ogun rẹ gbà rí pé ayédèrú àti magomago ibo kò ní wáyé rárá lásìkò ijoba tòun.

Ṣùgbọ́n kòkòrò kò jẹ ká gbádùn obì tó gbó, ọdún mẹta péré ni Yar'adua náà lo lórí aleefa, tí ikú fi pá ojú rẹ dé, tí kò sì dúró de asiko ìbò gbogbo gbòò miran.

Ibọwọ fún òfin ilẹ̀ wa

Ohun àrà kẹta tí Umar Yar'adua ṣe lórí aleefa ni pé ó jẹjẹ pé òun yóò máa bù ọwọ ńlá fún òfin ilẹ̀ wa yàtò si bí àwọn aṣáájú tó síwájú rẹ tí ń ṣe.

Ó sì ṣe àṣeyọrí pupọ nídìí ìlérí rẹ náà, gbogbo àṣẹ ile ẹjọ́ àti òfin ilẹ̀ wa lo tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ Nàìjíríà.

Ààrẹ àkọ́kọ́ to kọjú Boko Haram, ségun wọn

Ohun ìdùnnú miran ti aarẹ Umar Musa Yar'adua tún ṣe, tàwọn ọmọ Nàìjíríà kò fi ní gbàgbé rẹ ni pé, òun ni aarẹ àkọ́kọ́ to fojú wina ikọ asekupani Boko Haram, tó sì wá ọwọ rẹ bolẹ nígbà náà, kí ikọ ọ̀hún tún tó gberi dìde.

Bí ikọ afẹjẹwẹ náà sì ṣe ń fojú hàn síta, ní ìjọba rẹ koju wọn, to sì pá asiwaju ikọ náà, Muhammad Yusuf, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ikọ náà padà gberi, tó sì ń dààmú Nàìjíríà di òní yìí

Ìdáríjì àti sísan owó iranwọ fún ikọ ajijagbara Niger Delta:

Lára àwọn àṣeyọrí aarẹ tẹ́lẹ̀ tó di olóògbé yìí ni wíwà àlàáfíà ni agbegbe Niger-Delta tí àwọn ajijagbara tí ń bá ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà jẹ́.

Umar Yar'adua fi ori jin àwọn agbebọn náà, ó ní kí wọn jọ̀wọ́ ohun ijagun wọn, tó sì ń ṣàn owó iranwọ fún wọn.

Igbesẹ rẹ yìí ló mú kí àlàáfíà jọba lágbègbè Niger-Delta lásìkò tíẹ, tí ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà si dúró rẹ.

Gbogbo àwọn àṣeyọrí aare Umar Musa Yar'adua yìí lo si wa ni ìrántí àwọn ọmọ Nàìjíríà, tá sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tẹ si afẹ́fẹ́ rere

Umaru Musa Yar'Adua: Atiku, Saraki, Jonathan ń ṣè'rántí Ààrẹ tó lọ

Iku n pani, ilẹ n jẹ'yan. Ọjọ Aiku, ọjọ karun un oṣu karun un ni o pe ọdun mẹsan-an gerege ti aarẹ orilẹede Naijiria nigba kan ri, Umaru Musa Yar'adua re iwalẹ asa.

Ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria lo n ṣedaro aarẹ ana. Ninu wọn ni oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar wa.

Atiku to msọrọ lojun opo Twitter ni aarẹ tẹlẹ ri, Yar'adua jẹ alaanu eeyan, bẹẹ lo si fẹran orilẹede rẹ nigba to wa loke eepẹ.

Atiku gbadura pe ki Ọba oke ko dẹlẹ fun ẹni 're to lọ.

Ninu ọrọ tiẹ, aarẹ ana to tun figba kan jẹ igbakeji fun Aarẹ Yar'adua, Goodluck Jonathan ṣapejuwe Yar'Adua bi ọrẹ, iyekan ati ọga.

Jonathan ni Yar'Adua jẹ olori ti ko ni imọ tara ẹni nikan, bakan naa lo ṣapejuwe rẹ gẹgẹ ẹniti o maa n gbiyanju nigba gbogbo lati ri wi pe ifẹ orilẹede Naijiria siwaju ifẹ ọkan rẹ.

Adari ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja, Bukọla Saraki naa ko gbẹyin ninu awọn to n ṣe iranti aarẹ to lọ.

Saraki ni iwe rere ti Yar'Adua wu nigba to jẹ aarẹ Naijiria ti di ohun manigbagbe, bẹẹ lo gbadura pe ki aanu Eleduwa maa baa nibi kibi to ba wa.

Sẹnẹtọ Shehu Sani naa sọrọ iwuri nipa Yar'Adua, o ni aarẹ to lọ jẹ olotitọ eniyan ati oloṣelu ti kii figba kan bọkan ninu.

Sẹnẹtọ Saniu fikun ọrọ rẹ pe onirẹlẹ eniyan ni Yar'Adua jẹ, bakan naa lo gbadura pe ki Eleduwa Alijana ṣẹsan 're fun un.

Ọjọ karun un oṣu karun un ọdun 2010 ni Aarẹ Umaru Musa Yar'Adua jade laye.