You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus: Ọ̀gá iléèṣẹ́ tó n ṣe kọ́ńdọ́mù Durex sọ pé ìbálòpọ̀ dínkù lásìkò ìgbélé yìí
Laisi ani-ani, ibalopọ ti dinku lasiko konle-o-gbele nitori aarun coronavirus to wa lode.Ọga ileeṣẹ Reckitt Benckiser, ti wọn n ṣe rọba idaabobo Durex ti sọ pe awọn eeyan ko saa ba ni ibalopọ pẹlu ara wọn lasiko ajakalẹ aarun covid-19 yii.Laxman Narasimhan ni ọja rọba idaabobo ti lọọlẹ gan an lasiko yii koda to fi de orilẹede Uk.
O ṣalaye pe eleyi ṣẹlẹ nitori ofin iṣede to wa kaakiri agbaaye ko fawọn eeyan lanfaani lati ri ti ọrọ ibalopọ ro.
Narasimhan fikun ọrọ rẹ pe ọpọ lọkọ-laya gan ni ko sun mọ ara wọn mọ bi ti tẹlẹ ki coronavirus to de.Awọn nnkan mii bi ọṣẹ ifọwọ ati oogun ikọ olomi ti ileeṣẹ naa n ṣe si n ta warawara ṣugbọn ọja rọba idaabobo nikan lo wa lẹ.Ọga ileeṣẹ Reckitt Benckiser ni ọpọ eeyan papaa julọ nilẹ Gẹẹsi ati Italy ni ibaṣepọ wọn ko dọn mọran mọ lati igba ti ofin konle-o-gbele ti bẹrẹ.
Ṣaaju ni awọn onimọ kan sọ pe ọmọ bibi yoo pọ lọdun 2021, nitori pe ofin konile-o-gble ti mu ki ọpọ tọkọ-taya o wa papọ.
Rọ́bà ìdáàbòbò gbówó lórí! ìjọba Tanzania ko 30 Mílíọ̀nù rẹ̀ wọ̀lú
Awọn eleto ilera orilẹede Tanzania ti ko rọba idaabobo ọgbọn miliọnu wọ orilẹede wọn lati mu adinku ba
Ni orilẹede naa, ṣe ni awọn eniyan n kun yunmu yunmu nipa bi rọba idaabobo ṣe n gbowo lori sii plu bi ijọba ṣi ṣe n pese rẹ fun awọn eniyan to.
Akọroyin BBC, Gilian Kikowe ni awọn ile itura kan ni awọn agbegbe ti katakara pọ si ati ibi igbafẹ Dar es Salaam ko fun awọn eeyan ni nkan idaabobo yii lọfẹ mọ.
"Awọn ile itaja kan tilẹ n ta a ni ẹgbẹrun mẹta (3,000) ṣile iye owo ilẹ Tanzania eyi to jẹ bii $1; N351, o lee jẹ 5,000 tabi 10,000 ṣile ni iye owo ilẹ Tanzania iyẹn da lori iru ẹya rọba to ba jẹ.
"Awọn onibara gbudọ ni rọba idaabobo tiwọn bayii tori a o lagbara ati maa pin in lọfẹ mọ", oṣiṣẹ ile itura kan sọ fun BBC Swahili.
Igbakeji minisita fun eto ilera, Dokita Faustine Ndugulile ni awọn rọba idaabobo naa ti wa nikalẹ bayii fun lilo.
"A ti ra rọba idaabobo ọgbọn miliọnu. Ohun to yipada ni ọna ti a n gba pin in; awọn ajọ kan wa to n pin in tẹlẹ ṣugbọn nkan ti yi pada bayii a si ti ni ajọ mii ti yoo maa pin in.
Igbakeji minisita naa sọ pe awọn fẹ ki igbesẹ tuntun yii ko ipa gidi ki ipolongo awọn si kan awọn tọrọ yii kan gan ki rọba idaabobo si wa larọwọto.