You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Onitsha market fire: Ilé tó lé ni 100 ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná lọ ní Onitsha
Inu ibanujẹ ati ọfọ ni ọpọlọpọ awọn olugbe ilu Onitsha wa bayii, lẹyin ina to ṣẹyọ ni igba ti ọkọ elepo kan la'na ni ilu ọhun.
Aṣojukọroyin BBC ni Onitsha jabọ pe, lẹyin wakati mẹta ti ina ọhun bẹrẹ ni ọkọ panapana kan ṣoṣo ṣẹṣẹ yọju sibi iṣelẹ naa.
O ni ọkọ kan ṣoṣo yii ko to lati pa ina ọhun, nitori ina naa pọ ju iṣẹ ọkọ panapana kan ṣoṣo lọ.
- Gomina Makinde, àgbọ́gbọn'tí ni kẹ́ẹ gbọ́ àwọn ará Oyo o lórí sáà kejì 'torí...
- Àṣírí tú! Ọwọ Ọlọpàá ti tẹ ilé ìfìyà jẹni tí wọ́n fi ń pe ilé kéú ní Katsina
- Àgungùnlá! Bí Buhari wọ́gilé wíwọ bàálù olówó gọbọi fún òṣìṣẹ́ ìjọba kó ṣe aráàlú láǹfàní - SERAP
- Àwọn ojú oge Yollywood t'ọ́jà wọ́n ṣì ń tà wàràwàrà
Aṣoju BBC to wa nibẹ ni awọn ile to ba iṣẹlẹ naa lọ le ni ọgọrun, ti ọpọlọpọ awọn ara ilu naa si n pohunrere ẹkun lori iṣẹlẹ ọhun.
O ṣalaye pe ọja to ṣofo nibi ijamba ina naa le ni ẹgbẹgbẹrun miliọnu naira.
Lara awọn ile itaja to jona ni, ibi ti wọn ti n ta bata, aṣọ, kapẹẹti ati ẹya ara ọkọ.
Bakan naa lo ṣalaye pe awọn olugbe Onitsha ti n bere idi ti ileeṣẹ panapana ipinlẹ ọhun ko ṣe da wọn lohun lasiko ti wọn ke si wọn, ni kete ti ina naa bẹrẹ.
O ni ọkọ to n gbe igbọnsẹ lo gbiyanju lati pa diẹ ninu ina ọhun, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.
O sọ siwaju pe awọn eeyan ilu naa n binu si ijọba lọwọ, paapaa julọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana latari bi wọn ṣe kuna lati tete pa ina ọhun.
Nigba ti aṣoju BBC ṣe abẹwo si ileeṣẹ panapana ni ilu Akwa, ti ko jina si ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ, o ni gbogbo awọn oṣiṣe ileeṣẹ ọhun ti fẹsẹ fẹẹ nitori ibẹru awọn ọdọ ilu ti wọn sọ pe wọn fẹ se ikọlu si wọn.
Onitsha market fire: Buhari kẹdùn pẹlu ẹbí obìnrin tó kú àti ọmọ rẹ.
Ṣaaju lonii ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti banujẹ lori iṣẹlẹ ijamba ina to ṣọṣẹ ni Ipinlẹ Anambra lọjọru ọsẹ yii titi di ọjọbọ ọjọ keji.
Iroyin fi yewa pe, Obinrin kan ati ọmọ rẹ jona ti Aarẹ Buhari si ba gbogbo ebi ati ijọba ipinlẹ Anambra kẹdun pupọ.
Bayii, ko tii si ẹni to mọ iye ẹmi to ti sọnu latari iṣẹlẹ naa ṣugbọn akọọlẹ wa pe, ọgọọrọ eru ati dukia lo ti ṣofo.
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti fi aidunnu wọn han lori bi ijọba ko ṣe tete jigiri si ọrọ ọkọ agbepo to gbana ni Anambra.
Koda Gomina Sanwo-Olu to n tukọ ipinlẹ Eko naa kẹdun pẹlu Gomina Obiano akẹgbẹ rẹ atawọn eeyan ipinlẹ Anambra pe:
Awọn ọmọ Naijiria ni paa lẹẹkini ...ni ọrọ ijamba ina ninu ọja Anambra n di nitori baibai lo ku ti oju awọn oniṣowo n wo bayii
Ọpọ lo n di ẹbi ina yii ru gomina ipinlẹ Anambra pe ko gbe igbesẹ aabo lọwọ ina to yẹ fun ọja nla bii ti Onitsha yii
Ọpọ awọn eeyan ni wọn n gbadura fawọn to padanu ọja pe Oluwa a fofo ra ẹmi fun wọn ati pe ki ijọba pese ohun to yẹ ni amayedẹrun fawọn eeyan.
Koda, awọn miran sọrọ nipa Innoson Motors to n ṣe moto bii ti panapana ni Anambra ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ
Awọn eniyan Naijiria n beere ohun to ṣẹlẹ si ileeṣẹ panapana to wa ni ipinlẹ anambra tẹlẹ to fi jẹ panapana ipinlẹ Delta ni wọn duro de wa pa ina naa.
Ọpọ gbagbọ pe nitori pe Naijiria kii mura silẹ de ọjọ ogun lo n ṣokunfa wahala to n ṣẹlẹ yii
Ọkọ̀ agbépo tó gba iná ṣe àkóbá ní ọjà Onitsha
Bi eeyan ba jẹ ori ahun lọjọ to ti pẹ; to ba kọkọ de ibi ijamba ina to waye nilu Onitsha, o di dandan ko kawọ le ori.
Ijamba ina naa waye ni ọja Ochanya la gbọ pe o bẹrẹ lati nnkan bi aago mejila ọsan Ọjọru ti awọn kan si ni o jo titi wọ alẹ.
Ọkọ agbepo kan to lana ni wọn ni o fa ina naa ti o ṣakoba fọja Ochanja titi de agbegbe Upper Iweka.
Lẹyin ti awọn ọlọpaa ṣe ti ni ina naa ti lọlẹ, wọn ko ti i le fidi ọrọ mulẹ boya awọn eeyan ṣi yi wa ninu ina naa tabi bẹẹkọ.
Ninu awọn fọnran fidio to gba oju ayelujara niṣe ni awọn eeyan n sa asala fẹmi wọn ti awọn kan si n gbiyanju lati pa ina naa.
Lara awọn to ṣoju wọn ti BBC ba sọrọ ṣalaye pe ina naa ti ran de ọja Ochanja ati Relief Market ni Onitsha.
Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Anambra, Willie Obiano ti ṣe agbekalẹ́ igbimọ kan ti yoo tọpinpin ọrọ ina yi.
Gomina naa tun kesi awọn ti o farakasa ijamba ina yi lati wa si ipade kan lọjọ Aje to n bọ lati le mọ bi ijọba yoo ti ṣe ṣe iranwọ fun wọn.