Custom: A ti gbẹ́sẹ̀ lé ọjà tí oye rẹ̀ lé ní bílíọ́nù kan náírà lẹ́yìn tí a ti ibodè - ìjọba àpapọ̀

Ajọ aṣọbode Naijiria ni oun ti sẹ ẹdinku si bi wọn ṣe n ko ohun ija wọle sorilẹ-ede yii, lẹyin to gbe agadagodo sẹnu ibode to wọle si Naijiria.

Ọga agba fun ajọ naa, Hameed Ali lo sọ ọrọ yii, nibi ifọrọwerọ kan pẹlu awọn oniroyin lori iṣẹ ti wọn pe ni "Ex-Swift Response" ni Abuja.

O ni ajọ ọhun ti gbẹsẹ le kiko ohunkohun wọle si orilẹ-ede yii ni gbogbo ẹnu ibode ilẹ to wọle si Naijiria.

Ajọ naa ni wọn ti awọn ibode ọhun lati oṣu kẹjọ, ọdun 2019 latari ati lee jẹ ki ọrọ aje orilẹ-ede yii dagba sii.

Ni eyi to si ti n bi eso rere ti gbogbo oju le ri ka ninu okowo ati eto aabo Naijiria.

Ali fikun un pe, awọn ibode naa di titi latari ati lee dẹkun bi awọn kan ṣe n ko ọja wọle sorilẹ-ede yii lọna ti ko tọ.

O ni bayii, ọna to yẹ ni ẹnikẹni to ba fẹ ko ọja wọ Naijiria gbọdọ gba koo wọle ki o si pa owo ori fun Naijiria.

Hammed ni ọja ti wọn ti gbẹsẹ le lati igba ti wọn ti ti ibode Naijiria ni iye rẹ le ni biliọnu kan ati irinwo, ti ajọ ọhun si ti n pa owo ti ko din ni biliọnu marun un naira wọle sapo ijọba lojoojumọ Ilééṣẹ́ Aṣọ́bodè Naijiria n pa bílíọ̀nù N5.8 wọlé lójúmọ́ lẹ́yìn tíjọba ti ẹnu bodè -Ali.

O ṣalaye pe awọn eeyan Naijiria ni ẹtọ labẹ ofin lati rinrin ajo lọ sibikibi, ṣugbọn wọn ko fi aaye gba ẹnikẹni lati ko ohunkohun wọle si Naijiria lai gba aṣẹ.

Ọga aṣọbode ọhun ni ajọ naa ko ṣetan lati ṣi ẹnu ibode to wọle si orilẹ-ede yii.

O ni titi di igba ti awọn orilẹ-ede to yi Naijiria ka yoo fi tẹle ilana ti ajọ ECOWAS gbe kalẹ lori owo ṣiṣe lati orilẹ-ede kan si omiran.

Hammed pari ọrọ rẹ pe lati igba ti ajọ naa ti gbe kọkọrọ si ẹnu ibode, ọrọ aabo ti ṣẹnu ire ju ti tẹlẹ lọ.