LAUTECH: Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ló ń jẹ owó ọdun 2019 ní LAUTECH

Egbinrin ọtẹ, bi a ṣe n pakan ni ikan n ru.

O ti to ọjọ mẹta wayii ti ijọba ipinlẹ mejeeji ti wọn jumọ ni ileewe giga Ladoke Akintola ti n fi ẹsun gbogbo to nii ṣe pẹlu ipese owo fun akoso fasiti naa kan ara wọn.

Amọṣa nibayii awọn ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni ẹgbẹ Ọṣun forum ti n fi ẹsun kan awọn oṣiṣẹ fasiti naa ti wọn jẹ ọmọ ipinlẹ Ọyọ.

Wọn ni pe wọn n gbero lati kọlu Giwa fasiti naa atawọn oṣiṣẹ ibẹ ti wọn jẹ ọmọ ipinlẹ Ọṣun.

Nigba ti BBC News Yoruba gbe ọrọ naa tọ awọn igun mejeeji lọ, kọmiṣọna fun eto ẹkọ nipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Ṣangodoyin ṣalaye pe ko tọna ki oṣiṣẹ kọkan lati ipinlẹ yoowu to ba maa jẹ o kọlu awọn akẹgbẹ wọn nitori bo pẹ bo ya, ọrọ naa yoo ni iyanju.

Ọjọgbọn Sangodoyin ni gbogbo ọna ni ijọba ipinlẹ Ọyọ n yẹ lati rii pe ọrọ naa pari.

Ṣugbọn agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun, Ismail Omipidan ṣalaye pe ko daju pe ijọba ipinlẹ Ọyọ n wa ọna alaafia lati pẹtu si aawọ naa nitoripe gbogbo anfani alaafia ti gomina Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun ti la silẹ ni gomina Makinde ti kọ ipakọ si.

Bi o tilẹ jẹ pe Ọjọgbọn Ṣangodoyin ni adehun kọlọmu-dọmu iya rẹ mu ti igbimọ oluwadi labẹ amofin Ọlanipẹkun la kalẹ naa fe ku diẹ.

Adehun naa ni wọn ti sọ pe ki ijọba ipinlẹ Ọyọ maa mojuto ileẹkọṣẹ iṣegun oyinbo LAUTECHTH ni Ogbomọṣọ ki ipinlẹ Ọṣun si mojuto ti Ilu Oṣogbo.

Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun ni ko si ohun to jọọ rara nitori pe ileewe ẹkọṣẹ iṣegun to wa nilu Ogbomọṣọ ko si ninu iwe ofin to da fasiti LAUTECH silẹ, "atọwọda ipinlẹ Ọyọ ni"