You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yollywood: Odunlade fijó bẹ́ẹ, Lizzy padà sọ́dún 2012, Lateef gbàmì ẹ̀yẹ tuntun
Wọnyi ni diẹ lara awọn nnkan tawọn oṣere Yollywood ṣe lọsẹ yii ti wọn si gbe sori ayelujara nipa ara wọn.
Lizzy Anjọrin:
Ẹ jẹ ki a bẹrẹ pẹlu oṣere yii, Lizzy Anjọrin, lo fi ibeere lede lori oju opo Instagram rẹ pe kawọn ololufẹ oun sọ iru ọkọ ti oun n lo laarin ọdun 2012 si 2013.
Koda, o tun sọ wi pe ẹnikẹni to ba le sọ iru ọkọ ti oun n lo lọdun 2011; oun ṣetan lati fun iru ẹni bẹẹ lẹbun ẹgbẹrun un marun un owo naira.
Lizzy ṣalaye loju opo instagram rẹ pe ayelujara ti mu ayipada ba igbe aye eleyi to si n mu ọpọ eeyan parọ tawọn mii si n wuwa buruku kiri.
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, Aláàfin obìnrin àkọ́kọ́ rèé, tó ní nǹkan ọkùnrin
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Ṣẹ gbọ́ nípa Alájọ Ṣómólú, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
- Duro Ladipọ, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà àti ọmọ àlúfà tí kò gbàgbé àṣà ìbílẹ̀
- Ibi tí orí dá èmi Razak Olayiwola sí ni mò ń gbé- Ojopagogo
- "Mo fẹ́ pa ara mi torí ojú àbùkù tí wọn ń fi wò mí pé mo fi iṣẹ́ abẹ bímọ"
- Ṣé ẹ̀yin mọ orúkọ tí Yorùbá ń pé 'Necklace'?
- Wo orílẹ́èdè tí wọ́n tí ń dáwó ìsìnkú ara wọn pámọ́
Toyin Abraham:
Toyin Abraham ni tirẹ ṣo pe oun lọ tọ nigba mẹwaa laarin iṣẹju mẹẹdogun lati ori itage nigba ti oun n kopa ninu ere #Elevatorbaby pẹlu oyun ninu oun.
Toyin fikun ọrọ rẹ pe igba marun un ni oun lọ mu omi bakan naa laarin iṣẹju mẹẹdogun lori itage.
O ni oyun inu oun ti pe oṣu mẹfa nigba ti oun kopa ninu ere yii.
Afi ki gbogbo abiyamọ jere ọmọw ọn, oyun nini ko rọrun!
'Ìdí rèé tí mo fi ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fipá bámi lopọ̀ lọ́mọ ọdún méje lọ́gọ́ta ọdún sẹ́yìn'
Funke Akindele:
Funke Akindele fi fiimu to ṣẹṣẹ dari sita lori oju opo Instagram rẹ, eyi ti o pe akọle rẹ ni #Your Excellency.
O sọ nipa asiko ti ere naa yoo di wiwo ni kaakiri
Lẹyin to gboryin fun Baba Ibeji olowo ori Funkẹ pe o ku atilẹyin oun.
Laide Bakare:
Ọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu kẹwaa ni ọjọ ibi Laide Bakare, eyi to ṣe ni ilu Atlanta, nipinlẹ Georgia l'Amerika.
Oriṣiiriṣii fidio ni Laide fi soju opo Instagram rẹ eleyi to ṣayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.
Odunlada Adekola:
Ijo ni Odunlade Adekola fi bẹ ni tiẹ ninu fidio kan to fi soju opo Instagram rẹ.
Fidio yii lo ṣafihan bi Odunlade ṣe ko mọlẹ pẹlu Mike Edwards to wa lara awọn marun un to pegede julọ ninu eto BBNaija 2019 to ṣẹṣẹ pari
Femi Adebayo Salami:
Femi Adebayo Salami to jẹ ọmọ Ọga Bello fi aworan kan sori oju opo ayelujara rẹ eleyi to fi ṣalaye pe ohun kan to rọ oun lọrun ju lati maa ṣe naa ni ere ori itage.
Koda o ni oun le ṣee lọfẹẹ, bakan naa lo bi awọn ololufẹ rẹ lati sọ ohun ti wọn fẹran ju ni ti wọn lati maa ṣe.
Lateef Adedimeji:
Lọsẹ yii bakan naa ni oṣerekunrin ni, Lateef Adedimeji gba ami ẹyẹ Emperor Award Stylish Actor.
O ki gbogbo awọn eeyan to dibo fun un loju opo instagram rẹ, bẹẹ naa lo fi ami ẹyẹ ọhun sọri wọn.